ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb21 September ojú ìwé 3-16
  • Máa Lo Ìwé “Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!” Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Lo Ìwé “Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!” Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Lè Fi Ìwé “Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!” Kọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
    Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi—Apá Kìíní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
mwb21 September ojú ìwé 3-16
Tọkọtaya kan ń fi ìwé “Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì” wàásù fún ọkùnrin kan ní ibùdókọ̀.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Máa Lo Ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù

Inú wa dùn gan-an pé a ti láwọn ìwé tuntun tá a lè máa fi darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì! Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà bù kún wa bá a ṣe ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti sọ ọ̀pọ̀ èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mt 28:18-20; 1Kọ 3:6-9) Báwo la ṣe máa lo àwọn ìwé tuntun yìí?

Ọ̀nà tuntun làá máa gbà fi ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí náà, tẹ̀ lé àwọn àbá tó wà nísàlẹ̀ yìí nígbà tó o bá ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹnì kan sílẹ̀ tàbí tó o bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.a

  • Ẹ ka ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan, kẹ́ ẹ sì jíròrò ìbéèrè tó wà níbẹ̀

  • Ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n kọ “ka” sí, kó o sì ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ láti mọ bó ṣe lè fi í sílò

  • Ẹ wo àwọn fídíò tó wà ní ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan, kẹ́ ẹ sì fi àwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀ jíròrò ohun tẹ́ ẹ kọ́ nínú fídíò náà

  • Ẹ gbìyànjú láti parí ẹ̀kọ́ kan ní ìjókòó kan

Tó o bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì ni kó o kọ́kọ́ fún onílé kó o lè mọ̀ bóyá ó nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ rẹ. (Wo àpótí náà “Bó O Ṣe Lè Fi Ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò.”) Tẹ́ ẹ bá parí ẹ̀, tó o sì rí i pé ó wu onílé láti máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ, fún un ní ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì kẹ́ ẹ sì bẹ̀rẹ̀ láti ẹ̀kọ́ 04. Tó o bá ń fi ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde wa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹnì kan tẹ́lẹ̀, ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì ni kó o máa lò báyìí, kó o sì pinnu ibi tẹ́ ẹ ti máa bẹ̀rẹ̀.

Tọkọtaya kan náà ń fi ìwé “Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì” darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ọkùnrin yẹn nílé ẹ̀.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ OHUN TÓ O MÁA GBÁDÙN NÍNÚ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ RẸ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwọn nǹkan wo ni akẹ́kọ̀ọ́ máa kọ́ nínú ìwé tuntun yìí?

  • Kí nìdí tó fi yẹ kó o fi fídíò yìí han ẹni tó o fẹ́ kọ́ lẹ́kọ̀ọ́?

  • Àwọn nǹkan wo lo lè rọ akẹ́kọ̀ọ́ rẹ láti máa ṣe bẹ́ ẹ ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ?​—Wo “Ohun Tí Ẹ̀kọ́ Kọ̀ọ̀kan Dá Lé Àti Ohun Tó Yẹ Kí Akẹ́kọ̀ọ́ Ṣe”

a ÀKÍYÈSÍ: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò pọn dandan kẹ́ ẹ jíròrò apá tá a pè ní “Ṣèwádìí” nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́, síbẹ̀ rí i pé o ka àwọn ìtẹ̀jáde tá a tọ́ka sí, kó o sì wo àwọn fídíò tó wà níbẹ̀ tó o bá ń múra sílẹ̀. Ìyẹn á jẹ́ kó o mọ ohun tá wọ akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́kàn àti bó o ṣe lè ràn án lọ́wọ́. Ìwé yìí tó wà lórí ẹ̀rọ ní ìlujá sáwọn fídíò àtàwọn ìtẹ̀jáde tá a tọ́ka sí.

OHUN TÍ Ẹ̀KỌ́ KỌ̀Ọ̀KAN DÁ LÉ ÀTI OHUN TÓ YẸ KÍ AKẸ́KỌ̀Ọ́ ṢE

 

Ẹ̀KỌ́

OHUN TÓ DÁ LÉ

OHUN TÓ YẸ KÍ AKẸ́KỌ̀Ọ́ ṢE

1

01-12

Bí Bíbélì ṣe lè ràn án lọ́wọ́ àti bó ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run tó fún wa ní Bíbélì

Rọ̀ ọ́ pé kó máa ka Bíbélì, kó máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ sílẹ̀, kó sì máa wá sípàdé

2

13-33

Ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún wa àti ọ̀nà tó fẹ́ ká máa gbà jọ́sìn òun

Rọ̀ ọ́ pé kó máa sọ ohun tó ń kọ́ fáwọn mí ì, kó sì gbìyànjú láti di akéde

3

34-47

Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ káwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ máa ṣe

Rọ̀ ọ́ pé kó ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, kó sì ṣèrìbọmi

4

48-60

Bá a ṣe lè máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run títí láé

Jẹ́ kó mọ bó ṣe lè fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ àti bó ṣe lè túbọ̀ máa tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run

BÓ O ṢE LÈ FI ÌWÉ GBÁDÙN AYÉ RẸ TÍTÍ LÁÉ!​—ÌBẸ̀RẸ̀ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ BẸ̀RẸ̀ ÌJÍRÒRÒ

Bíi tàwọn àṣàrò kúkúrú wa, àwọn ìbéèrè tá a lè fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò wà lẹ́yìn ìwé yìí. Torí náà, o lè gbìyànjú àwọn àbá yìí:

  • Béèrè ìbéèrè tó wà lẹ́yìn ìwé náà, kó o sì ní kẹ́ni náà yan ìdáhùn tó rò pé ó tọ́

  • Ka Sáàmù 37:29 láti dáhùn ìbéèrè náà

  • Ẹ jíròrò apá tá a pè ní “Àǹfààní Wo Ló Máa Ṣe Ẹ́?” Tí àkókò bá wà, ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a tọ́ka sí, kó o sì ṣàlàyé àwọn àwòrán tó wà níbẹ̀

  • Ẹ jíròrò ìbéèrè tó tẹ̀ lé e, kó o sì gbìyànjú láti fi ẹ̀kọ́ kìíní bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́