ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/98 ojú ìwé 8
  • Ó Yẹ Kí Àwọn Aládùúgbò Wa Gbọ́ Ìhìn Rere

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Yẹ Kí Àwọn Aládùúgbò Wa Gbọ́ Ìhìn Rere
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wàásù fún “Ènìyàn Gbogbo”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Fi Àwọn Ìwé Pẹlẹbẹ Pòkìkí Ìhìn Rere Ìjọba Náà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Ẹ Jẹ́ Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọrun—Ní Lílo Àwọn Ìwé Pẹlẹbẹ
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Tẹ́tí sí Ọlọ́run
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 7/98 ojú ìwé 8

Ó Yẹ Kí Àwọn Aládùúgbò Wa Gbọ́ Ìhìn Rere

1 Ìfẹ́ Ọlọ́run ni “pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) “Gbogbo onírúurú ènìyàn” yóò ní gbogbo aládùúgbò wa nínú. Mímú ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ wọn ń béèrè pé kí àwọn ìgbékalẹ̀ wa jẹ́ onírúurú kí a sì ronú nípa ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tí a bá bá pàdé yóò lọ́kàn-ìfẹ́ sí.—1 Kọ́r. 9:19-23.

2 Ètò àjọ Jèhófà ti pèsè àwọn irin iṣẹ́ tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti dé ọkàn-àyà àwọn tí wọ́n “ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun.” (Ìṣe 13:48) Ní oṣù July títí dé oṣù September, a óò máa fi àdìpọ̀ ìwé méjì tàbí mẹ́rin lọni ní owó pọ́ọ́kú. Iwe Itan Bibeli Mi wà lára àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí. Ìtẹ̀jáde yìí lè ran tèwe tàgbà lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Bíbélì ń fi kọ́ni. Ẹ jẹ́ kí a wo bí a ṣe lè lo ìwé yìí ní oṣù July títí dé oṣù September láti bójú tó àwọn àìní tẹ̀mí ti àwọn aládùúgbò wa.

3 Ní ìsàlẹ̀, ìwọ yóò rí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn àbá tí ó lè wúlò nígbà tí o bá ń fi ìwé Itan Bibeli lọni. Àbá kọ̀ọ̀kan ní nínú (1) ìbéèrè kan tí ń múni ronú jinlẹ̀ fún bíbẹ̀rẹ̀ ìjíròrò, (2) ìtọ́ka sí ibi tí a ti lè rí kókó ìbánisọ̀rọ̀ nínú ìwé náà, àti (3) ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó bá a mu tí a lè kà ní àkókò ìjíròrò. Ó lè fi ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ mú kí ìgbékalẹ̀ náà kún rẹ́rẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú bí ẹni náà bá ṣe dáhùn padà.

Ilẹ̀ ayé yóò ha di párádísè kan láé bí?—Ìtàn 71; Ìṣí. 21:3, 4.

O ha ti ṣe kàyéfì rí nípa bí ìwọ yóò ṣe tu ẹnì kan tí ó ti pàdánù ẹnì kan tí ó nífẹ̀ẹ́ nínú ikú nínú bí?—Ìtàn 92; Jòh. 5:28, 29.

Ìrètí wo ni o rò pé ó wà tí a lè fi ran àwọn ènìyàn tí ń ṣàìsàn lọ́wọ́?—Ìtàn 96; Aísá. 33:24.

O ha ti ṣe kàyéfì rí nípa ohun tí Jésù Kristi ń ṣe nísinsìnyí bí?—Ìtàn 104; Kól. 1:13, 14.

Ayé yóò ha bọ́ lọ́wọ́ ìwà búburú láé bí?—Ìtàn 114; Sm. 37:9, 10.

Ta ni Ọlọ́run yóò pa mọ́ láti gbé nínú Párádísè?—Ìtàn 116; 1 Jòh. 2:17.

4 Àwọn Ìwé Mìíràn: Onírúurú ìwé mìíràn ni ó wà lára àkànṣe ìfilọni fún oṣù July títí dé oṣù September. Níbikíbi tí ó bá ti yẹ bẹ́ẹ̀, a lè fi àwọn ìwé yòókù tí ó jẹ́ ara àkànṣe ìfilọni lọ àwọn ènìyàn tí a bá bá pàdé. O lè ṣàtúnyẹ̀wò àwọn àbá tí ó wà ní ojú ìwé 21 sí 24 nínú ìwé Reasoning tàbí ní ojú ìwé 13 sí 16 nínú ìwé kékeré Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, kí o sì múra àwọn ìgbékalẹ̀ ṣókí tí ó lè ru àwọn ènìyàn wọ̀nyí sókè.

5 Nígbà gbogbo, ète tí a fi ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ yẹ kí ó máa jẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, yálà nígbà ìkésíni àkọ́kọ́ tàbí nígbà ìpadàbẹ̀wò tí ó tẹ̀ lé e. Láti ṣe èyí, àní bí onílé kò bá tilẹ̀ gba èyíkéyìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa pàápàá, a lè ṣètò láti ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀ nítorí kí a lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí o kò bá tíì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí ìwé Ìmọ̀, bẹ̀rẹ̀ sí lo ọ̀kan nínú wọn bí ó bá ti ṣeé ṣe kí ó yá tó.

6 Nínú àkàwé Jésù nípa ará Samáríà tí ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ará àdúgbò, ó mú kí ó ṣe kedere pé aládùúgbò tòótọ́ ni ẹni tí ó lo ìfẹ́ àti inú rere láti ran ẹlòmíràn tí ó wà nínú wàhálà lọ́wọ́. (Lúùkù 10:27-37) Àwọn aládùúgbò wa wà nínú wàhálà tẹ̀mí. Ó yẹ kí wọ́n gbọ́ ìhìn rere. Ẹ jẹ́ kí a fọwọ́ gidi mú ẹrù iṣẹ́ wa láti ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú wọn kí a sì tipa báyìí fi hàn pé a jẹ́ ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi.—Mát. 24:14; Gál. 5:14.

7 A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún Ìwé Mímọ́ nípasẹ̀ èyí tí ‘ènìyàn Ọlọ́run fi lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.’ (2 Tím. 3:17) A tún kún fún ìmoore fún irú àwọn ìtẹ̀jáde bí ìwé Itan Bibeli àti àwọn ìwé yòókù tí ó wà lára àwọn àkànṣe ìfilọni. A mọrírì ìwúlò wọn, a sì láyọ̀ pé a lè fi wọ́n lọ àwọn ẹlòmíràn ní oṣù July títí dé oṣù September.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́