Ẹ Jẹ́ Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọrun—Ní Lílo Àwọn Ìwé Pẹlẹbẹ
1 Gbogbo ìránṣẹ́ Jehofa tí ó ti ṣe ìyàsímímọ́ ni ó ní ẹrù-iṣẹ́ láti ṣàjọpín nínú iṣẹ́ kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ìjẹ́pàtàkì ẹrù-iṣẹ́ yìí di èyí tí ó ṣe kedere nígbà tí a bá lóye pé ẹni tí ó ni gbogbo ọlá-àṣẹ ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀-ayé ni ó fún wa ní àṣẹ láti ‘sọ awọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn, ní kíkọ́ wọn.’ (Matt. 28:18-20) Nítorí náà, ṣíṣàjọpín nínú wíwàásù ìhìnrere ń béèrè pé kí a di olùkọ́ni!—2 Tim. 2:2.
2 Ní August, a lè lo òye-iṣẹ́ ìkọ́ni wa nígbà tí a bá ń fi àwọn ìwé pẹlẹbẹ lọni. A lè yan díẹ̀ lára àwọn èròǹgbà Ìwé Mímọ́ tí ń ru ìfẹ́ sókè tí ó wà nínú wọn kí a sì múra àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ sílẹ̀ tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀.
3 Nígbà tí o bá ń fi ìwé pẹlẹbẹ náà “Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?” lọni, o lè sọ pé:
◼ “A ti késí ọ̀pọ̀ nínú àwọn aládùúgbò rẹ, a sì rí i pé wọ́n ń ṣàníyàn nípa ìwà-ọ̀daràn, ìkópayàbáni, àti ìwà-ipá tí ń yára ga sókè. Ní èrò tìrẹ, èéṣe tí àwọn wọ̀nyí fi di ìṣòro ńlá tó bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ó fà wá lọ́kàn mọ́ra láti rí i pé Bibeli ti sọ tẹ́lẹ̀ pé èyí yóò ṣẹlẹ̀. [Ka 2 Timoteu 3:1-3.] Ṣàkíyèsí pé èyí yóò ṣẹlẹ̀ ní ‘awọn ọjọ́ ìkẹyìn.’ Èyí dọ́gbọ́n fi hàn pé ohun kan yóò wá sí òpin láìpẹ́. Kí ni o rò pé ó jẹ́?” Jẹ́ kí ó fèsì. Ṣí i sí ojú-ìwé 22, fi àwòrán náà hàn án, kí o sì jíròrò ọ̀kan tàbí méjì lára àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ tí a ṣàyọlò rẹ̀ ní ojú-ìwé náà. Lẹ́yìn náà fi ìwé pẹlẹbẹ náà lọ̀ ọ́ fún ọrẹ ₦24 kí o sì ṣètò láti padà wá lẹ́yìn náà láti ṣàlàyé ìdí tí a fi gbàgbọ́ pé àwọn ìbùkún wọ̀nyí súnmọ́lé.
4 O lè fẹ́ láti lo ọ̀nà ìyọsíni yìí nígbà tí o bá ń fi ìwé pẹlẹbẹ náà “Ki Ni Ète Igbesi-Aye—Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?” lọni:
◼ “Ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ń dojúkọ ìṣòro ní gbígbìyànjú láti wá ète gidi nínú ìgbésí-ayé. Nígbà tí àwọn díẹ̀ ń gbádùn ayọ̀ níwọ̀nba, ọ̀pọ̀ jùlọ ń gbé ìgbésí-ayé tí ó kún fún ìjákulẹ̀ àti ìjìyà. Ìwọ ha rò pé bí Ọlọrun ti fẹ́ kí a gbé ìgbésí-ayé nìyí bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bibeli fi hàn pé Ọlọrun fẹ́ kí a gbé nínú ayé kan bí èyí.” Fi àwòrán tí ó wà ní ojú-ìwé 21 hàn án, lẹ́yìn náà ṣí i sí ojú-ìwé 25 àti 26, ìpínrọ̀ 4 sí 6, kí o sì ṣàlàyé ohun tí ó ti ṣèlérí. Fi ìwé pẹlẹbẹ náà lọ̀ ọ́ fún iye tí ó jẹ́. Gbé ìbéèrè yìí dìde fún ìjíròrò nígbà tí o bá padà wá: “Báwo ní a ṣe lè ní ìdánilójú pé Ọlọrun yóò mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ?”
5 O lè fi ìwé pẹlẹbẹ náà “Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!” lọni nípa fífi gbogbo àwòrán tí ó wà ní iwájú àti ẹ̀yìn ìwé náà hàn kí o sì béèrè pé:
◼ “Ìwọ yóò ha fẹ́ láti gbé nínú ayé tí ó kún fún àwọn ènìyàn aláyọ̀ bí èyí bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bibeli sọ fún wa pé Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ àwọn ènìyàn ó sì fẹ́ kí wọ́n gbé títíláé nínú ayọ̀ lórí ilẹ̀-ayé yìí.” Ṣí i sí àwòrán 49, kí o sì ka ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí. Lẹ́yìn náà, fi àwòrán 50 hàn án, kí o sì ṣàlàyé ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe bí a bá fẹ́ láti gbé nínú Paradise yìí. Fi ìwé pẹlẹbẹ náà lọ̀ ọ́ fún iye owó tí ó jẹ́ kí o sì ṣèlérí láti padà wá láti jíròrò ìdí tí ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi fi ṣe pàtàkì tóbẹ́ẹ̀.
6 Ó máa ń dùn mọ́ Jehofa nínú nígbà tí a bá jẹ́ kí ‘ìlọsíwájú wa farahàn kedere nípa fífiyèsí ẹ̀kọ́ wa.’ (1 Tim. 4:15, 16) Àwọn ìwé pẹlẹbẹ wa lè jẹ́ ìrànwọ́ gidi fún wa nínú àwọn ìsapá wa láti ṣèrànlọ́wọ́ fún àwọn wọnnì tí ń yánhànhàn láti gbọ́ “ìhìnrere ohun rere.”—Isa. 52:7.