Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
1. Báwo làwọn Kristẹni ajíhìnrere ṣe dà bí àwọn oníṣẹ́ ọnà?
1 Oríṣiríṣi irinṣẹ́ làwọn oníṣẹ́ ọnà máa ń lò. Àwọn irin iṣẹ́ kan wà tí wọ́n máa ń lò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó sì lójú iṣẹ́ tí wọ́n fi ń ṣe, nígbà tó sì jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń lo àwọn míì. Àwọn oníṣẹ́ ọnà tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ máa ń ní àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n mọ̀ ọ́ lò dáadáa nínú àpótí irinṣẹ́ wọn nígbà gbogbo. Bíbélì gba àwa Kristẹni níyànjú pé ká máa kópa déédéé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, ká sì jẹ́ “aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú.” (2 Tím. 2:15) Èwo ló ṣe pàtàkì jù lọ nínú àwọn ohun tá a fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló gbawájú jù lọ nínú àwọn ohun tá a fi ń ‘sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.’ (Mát. 28:19, 20) Torí náà, ó yẹ ká di ọ̀jáfáfá nínú bá a ṣe ń “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” Àmọ́, àwọn ohun míì tún wà tá a sábà máa ń lò láti fi kọ́ àwọn èèyàn, ó sì yẹ kí gbogbo wa kọ́ bá a ṣe lè lò wọ́n lọ́nà tó já fáfá láti fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.—Òwe 22:29.
2. Àwọn ohun pàtàkì wo la fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́?
2 Àwọn Ohun Pàtàkì Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́: Àwọn nǹkan míì wo la fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, yàtọ̀ sí Bíbélì? Ní pàtàkì, ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? ni ìwé tá a fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa bá ti parí ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, a máa ń fi ìwé ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’ kọ́ ọ ní ọ̀nà tó lè gbà máa fi àwọn ìlànà inú Bíbélì sílò lójoojúmọ́. Torí náà, ó yẹ ká mọ àwọn ìwé méjèèjì yìí lò lọ́nà tó já fáfá. Ó tún yẹ ká fi àwọn ìwé pẹlẹbẹ kan kún àwọn ìwé tá a fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! wà lára àwọn ìwé tá a fi ń bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tí àwọn èèyàn tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ ìwé kà, àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ sí àwọn ìtẹ̀jáde wa ní èdè tí wọ́n ń sọ tàbí tí kò sí ìtẹ̀jáde wa kankan lédè wọn bá wà ní ìpínlẹ̀ wa, a lè máa fi ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Ìwé náà, Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní? ni ìwé pàtàkì tá a fi ń darí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá sínú ètò Ọlọ́run. Ó yẹ ká tún mọ bá a ṣe lè lo àwọn fídíò tó máa jẹ́ ká lè sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, irú bíi, Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?, Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? àti Ṣé Ọlọ́run Ní Orúkọ?
3. Kí la máa kọ́ nínú àwọn àpilẹ̀kọ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tó ń bọ̀?
3 A máa kọ́ bá a ṣe lè lo àwọn kan lára àwọn ohun tá a fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó já fáfá nínú àwọn àpilẹ̀kọ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tó ń bọ̀. Bí a ṣe ń sapá láti lo àwọn ohun tá a fi ń kọ́ni lọ́nà tó já fáfá, ńṣe là ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ. Dúró nínú nǹkan wọ̀nyí, nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.”—1 Tím. 4:16.