ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb21 September ojú ìwé 7
  • Máa Lo Àwọn Ohun Èlò Ìwádìí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Lo Àwọn Ohun Èlò Ìwádìí
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Lo Ìbéèrè
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Jẹ́ Kí Jèhófà Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Nípasẹ̀ Àdúrà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Máa Lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
mwb21 September ojú ìwé 7

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ | JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀

Máa Lo Àwọn Ohun Èlò Ìwádìí

Jèhófà ti fún wa láwọn nǹkan tó lè mú ká já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ, a ní oríṣiríṣi fídíò, ìwé àṣàrò kúkúrú, ìwé ìròyìn, ìwé pẹlẹbẹ, ìwé ńlá àti Bíbélì tó jẹ́ olórí irinṣẹ́ wa. (2Ti 3:16) Ó tún fún wa láwọn ohun èlò ìwádìí kó lè rọrùn fún wa láti ṣàlàyé Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, a ni Watchtower Library, JW Library®, Àká Ìwé Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì (ti Watchtower), àti Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Wàá máa láyọ̀ tó o bá ń lo àwọn ohun èlò yìí láti túbọ̀ walẹ̀ jìn kó o lè rí àwọn ìṣúra tẹ̀mí tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ káwọn náà lè mọ bá a ṣe ń lo àwọn ohun èlò yìí. Ìyẹn á jẹ́ kó rọrùn fáwọn náà láti máa wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọn.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀​—MÁA LO ÀWỌN NǸKAN TÍ JÈHÓFÀ PÈSÈ—​ÀWỌN OHUN ÈLÒ ÌWÁDÌÍ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwòrán látinú fídíò “Jẹ́ Kí Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn Máa Fún Ẹ Láyọ̀​—Máa Lo Àwọn Nǹkan Tí Jèhófà Pèsè—​Àwọn Ohun Èlò Ìwádìí.” Jade ń ṣàlàyé fún Neeta pé ṣe làwọn nǹkan tó wà láyé kan ṣàdédé wà.

    Kí ni Jade sọ tó fi hàn pé kò gbà pé Ọlọ́run ló dá àwọn nǹkan?

  • Àwòrán látinú fídíò “Jẹ́ Kí Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn Máa Fún Ẹ Láyọ̀​—Máa Lo Àwọn Nǹkan Tí Jèhófà Pèsè—​Àwọn Ohun Èlò Ìwádìí.” Neeta ń ṣàyẹ̀wò àwọn ìsọfúnni nípa ìṣẹ̀dá nínú “Ìwé Ìwádìí.”

    Ibo ni Neeta ti ṣèwádìí lórí ọ̀rọ̀ náà?

  • Àwòrán látinú fídíò “Jẹ́ Kí Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn Máa Fún Ẹ Láyọ̀​—Máa Lo Àwọn Nǹkan Tí Jèhófà Pèsè—​Àwọn Ohun Èlò Ìwádìí.” Inú Neeta ń dùn bó ṣe ń ṣàlàyé àwọn ìsọfúnni tó rí fún Jade.

    À ń láyọ̀ bá a ṣe ń rí àwọn ìṣúra tẹ̀mí, tá a sì ń sọ ohun tá a kọ́ fáwọn míì

    Kí ló jẹ́ kí Neeta mọ ohun tó máa ran Jade lọ́wọ́?

  • Àǹfààní wo ni Neeta rí nígbà tó lo àwọn ohun èlò ìwádìí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́