MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ | JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀
Máa Lo Ìbéèrè
“Ọlọ́run aláyọ̀” ni Jèhófà, ó sì fẹ́ ká gbádùn iṣẹ́ ìwàásù. (1Ti 1:11) Ayọ̀ wa á máa pọ̀ sí i tá a bá túbọ̀ ń já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Tá a bá ń béèrè ìbéèrè, ó máa wu àwọn èèyàn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, á sì jẹ́ kó rọrùn fún wa láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Ìbéèrè tún máa ń jẹ́ káwọn èèyàn ronú jinlẹ̀. (Mt 22:41-45) Tá a bá ń béèrè ìbéèrè, tá a sì ń tẹ́tí sílẹ̀ táwọn èèyàn bá ń dáhùn, ṣe ló dà bí ìgbà tá à ń sọ pé, ‘O ṣe pàtàkì sí mi.’ (Jem 1:19) Ìdáhùn ẹni náà máa jẹ́ ká mọ ohun tá a máa sọ.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀—TÚBỌ̀ JÁ FÁFÁ—MÁA LO ÌBÉÈRÈ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Àwọn ìwà tó dáa wo ni Jade ní?
Àwọn ìbéèrè wo ni Neeta bi Jade láti fa ojú ẹ̀ mọ́ra?
Àwọn ìbéèrè wo ni Neeta bi Jade tó mú kó túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀?
Àwọn ìbéèrè wo ni Neeta bi Jade tó mú kó ronú jinlẹ̀?