TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ | JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀
Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Ní Àjọṣe Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Jèhófà
Jèhófà fẹ́ ká sin òun torí pé a nífẹ̀ẹ́ òun. (Mt 22:37, 38) Ìfẹ́ táwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa bá ní fún Jèhófà ló máa mú kí wọ́n ṣe àwọn àyípadà tó yẹ, kí wọ́n má sì bọ́hùn tí wọ́n bá kojú ìṣòro. (1Jo 5:3) Ìfẹ́ yìí kan náà ló máa mú kó wù wọ́n láti ṣèrìbọmi.
Ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn. Bi wọ́n láwọn ìbéèrè bíi: “Kí ni ohun tá a jíròrò yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?” tàbí “Báwo ni ohun tá a jíròrò yìí ṣe jẹ́ kó o mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ?” Jẹ́ kí wọ́n rí bí Jèhófà ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbèésí ayé wọn. (2Kr 16:9) Sọ àpẹẹrẹ àwọn ìgbà tí Jèhófà dáhùn àdúrà pàtó tó o gbà, kó o sì gbà wọ́n níyànjú pé káwọn náà kíyè sí bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àdúrà wọn. Kò sí àní-àní pé inú wa máa dùn gan-an tá a bá rí bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa ṣe túbọ̀ ń sapá láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ RAN ÀWỌN TÓ Ò Ń KỌ́ LẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ LỌ́WỌ́ LÁTI NÍ ÀJỌṢE TÍMỌ́TÍMỌ́ PẸ̀LÚ JÈHÓFÀ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Ìṣòro wo ni Jade dojú kọ?
Báwo ni Neeta ṣe ran Jade lọ́wọ́?
Kí ló mú kí Jade borí ìṣòro náà?