ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb21 November ojú ìwé 15
  • Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Máa Dá Kẹ́kọ̀ọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Máa Dá Kẹ́kọ̀ọ́
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Ní Àjọṣe Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Jáwọ́ Nínú Ìwà Àìmọ́
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Máa Lo Ìbéèrè
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
mwb21 November ojú ìwé 15

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ | JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀

Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Máa Dá Kẹ́kọ̀ọ́

Kì í ṣe ohun tá à ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa nìkan ló máa jẹ́ kí wọ́n lóye òtítọ́, tá sì jẹ́ kí wọ́n dẹni tẹ̀mí. (Mt 5:3; Heb 5:12–6:2) Ó tún ṣe pàtàkì kí wọ́n máa wáyè láti kẹ́kọ̀ọ́ fúnra wọn.

Àtìbẹ̀rẹ̀ ni kó o ti jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ mọ bó ṣe lè máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀, kó o sì máa fún un níṣìírí láti máa ṣe bẹ́ẹ̀. (mwb18.03 6) Sọ fún un pé ó yẹ kó máa fi àdúrà bẹ̀rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tó bá fẹ́ dá kẹ́kọ̀ọ́. Jẹ́ kó mọ bó ṣe lè rí àwọn ìtẹ̀jáde tó lè lò fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ lórí ìkànnì. Jẹ́ kó mọ bó ṣe lè máa rí àwọn nǹkan tuntun tó wà lórí ìkànnì jw.org àti ètò tẹlifíṣọ̀n JW. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, jẹ́ kó mọ̀ pé ó yẹ kó máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, kó máa múra ìpàdé sílẹ̀, kó sì máa ṣèwádìí nípa àwọn ìbéèrè tó bá ní. Jẹ́ kó mọ̀ pé ó yẹ kó máa ronú jinlẹ̀ lórí àwọn nǹkan tó ń kọ́.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ RAN ÀWỌN TÓ Ò Ń KỌ́ LẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ LỌ́WỌ́ LÁTI MÁA DÁ KẸ́KỌ̀Ọ́, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwòrán látinú fídíò “Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Máa Dá Kẹ́kọ̀ọ́.” Jade sọ fún Neeta pé ohun tó bá wọ òun lọ́kàn lòun máa ń rántí.

    Báwo ni Neeta ṣe jẹ́ kí Jade mọ̀ pé ìkẹ́kọ̀ọ́ kọjá kéèyàn kàn fàlà sí ìdáhùn?

  • Àwòrán látinú fídíò “Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Máa Dá Kẹ́kọ̀ọ́.” Neeta jẹ́ kí Jade mọ bó ṣe lè wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè rẹ̀ nínú Bíbélì.

    Kí ló jẹ́ kí Jade gbà pé ó bọ́gbọ́n mu bí Jèhófà ṣe sọ pé a ò gbọ́dọ̀ ṣe ìṣekúṣe?

  • Àwòrán látinú fídíò “Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Máa Dá Kẹ́kọ̀ọ́.” Jade jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀, ó sì ń ṣàṣàrò lórí ẹsẹ Bíbélì kan.

    Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ mọ bó ṣe lè máa dá kẹ́kọ̀ọ́ àti bó ṣe lè máa fi ohun tó ń kọ́ sílò

    Kí ni Neeta jẹ́ kí Jade mọ̀ nípa àṣàrò?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́