ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb21 July ojú ìwé 9
  • Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Lo Ìbéèrè
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Máa Lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Jẹ́ Kí Jèhófà Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Nípasẹ̀ Àdúrà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Jáwọ́ Nínú Ìwà Àìmọ́
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
mwb21 July ojú ìwé 9

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ | JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀

Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn

Téèyàn bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run látọkàn wá, á rọrùn fún un láti ṣègbọràn sí i. (Owe 3:1) Torí náà, a gbọ́dọ̀ sapá láti rí i pé ohun tá à ń kọ́ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

Tó o bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, má kàn ṣàlàyé ẹ̀kọ́ òtítọ́ fún un, ṣe ni kó o jẹ́ kó rí bí ohun tó ń kọ́ ṣe kàn án àti bó ṣe lè mú kí àjọṣe ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i. Jẹ́ kó mọyì àwọn ìlànà Jèhófà, kó sì mọ ìdí tó fi fún wa láwọn ìlànà yẹn, ìyẹn á jẹ́ kó gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, pé ìre wa ló ń wà àti pé Ọlọ́run òdodo ni. Máa fọgbọ́n béèrè ìbéèrè tá jẹ́ kó ronú jinlẹ̀, kó sì sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀. Ràn án lọ́wọ́ kó lè ronú nípa àǹfààní tá rí tó bá jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí ò dáa. Inú tìẹ náà máa dùn, tó o bá rí i pé akẹ́kọ̀ọ́ ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà látọkàn wá.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀​—TÚBỌ̀ JÁ FÁFÁ—​JẸ́ KÍ Ọ̀RỌ̀ RẸ WỌNI LỌ́KÀN, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Jẹ́ Kí Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn Máa Fún Ẹ Láyọ̀​—Túbọ̀ Já Fáfá​—Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn.’ Neeta ń béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ Jade nígbà tó ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀.

    Kí nìdí tí Neeta fi béèrè lọ́wọ́ Jade pé: “Ṣé ẹ tún pa dà ronú lórí àwọn nǹkan tá a sọ lọ́jọ́ Monday?”

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Jẹ́ Kí Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn Máa Fún Ẹ Láyọ̀​—Túbọ̀ Já Fáfá​—Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn.’ Neeta ń ṣàlàyé ẹsẹ Bíbélì kan fún Jade.

    Báwo ni Neeta ṣe jẹ́ kí Jade rí i pé ìfẹ́ ló mú kí Jèhófà fún wa láwọn ìlànà ẹ̀?

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Jẹ́ Kí Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn Máa Fún Ẹ Láyọ̀​—Túbọ̀ Já Fáfá​—Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn.’ Jade ń fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí Neeta ń sọ.

    Tá a bá jẹ́ kọ́rọ̀ wa wọ akẹ́kọ̀ọ́ wa lọ́kàn, ó máa wù ú láti tẹ̀ síwájú

    Kí ni Neeta sọ tó jẹ́ kí Jade rí bó ṣe lè fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́