August 9-15
DIUTARÓNÓMÌ 24-26
Orin 137 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Òfin Tí Jèhófà Ṣe Fi Hàn Pé Ó Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Obìnrin”: (10 min.)
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí: (10 min.)
Di 24:1—Kí nìdí tí kò fi yẹ ká gbà pé òfin yìí á jẹ́ kó rọrùn fún ọkọ kan láti kọ ìyàwó ẹ̀ sílẹ̀? (it-1 640 ¶5)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min.) Di 26:4-19 (th ẹ̀kọ́ 10)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ tí wọn ò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 1)
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Fún ẹni náà ní ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. (th ẹ̀kọ́ 2)
Àsọyé: (5 min.) w19.06 23-24 ¶13-16—Àkòrí: Báwo La Ṣe Lè Dúró Ti Ẹni Tí Ọkọ Tàbí Aya Ẹ̀ Kú? (th ẹ̀kọ́ 20)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Máa Hùwà Sáwọn Àgbà Obìnrin Bí Ìyá, Àwọn Ọ̀dọ́bìnrin Bí Ọmọ Ìyá”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Máa Fi Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn Sáwọn—Opó Àtàwọn Ọmọ Aláìníbaba.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) rr orí 12 ¶1-6, fídíò ohun tó wà ní orí 12 àti àpótí 12A
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.)
Orin 101 àti Àdúrà