Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ August 3
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ AUGUST 3
Orin 63 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 28 ìpínrọ̀ 10 sí 17 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 18-20 (8 min.)
No. 1: 1 Àwọn Ọba 18:30-40 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìdí Tí Àwọn Olóòótọ́ Ìránṣẹ́ Jèhófà Fi Máa Ń Láyọ̀ (5 min.)
No. 3: Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ran Àwọn Ọmọ Lọ́wọ́?—igw ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 1 àti 2 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: ‘Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn.’ —Mát. 28:19, 20.
10 min: Fi Àwọn Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù August. Ìjíròrò. Kọ́kọ́ fi àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé yìí ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni. Lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin.
10 min: Jàǹfààní Nínú Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́. Ìjíròrò. Fi àsọyé oníṣẹ̀ẹ́jú márùn-ún tó dá lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2015 bẹ̀rẹ̀ apá yìí. Lẹ́yìn náà, ní kí àwọn ará sọ ìgbà tí wọ́n máa ń ka ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́. Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, fún àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n máa lo ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
Orin 26 àti Àdúrà