Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 23
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JANUARY 23
Orin 89 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 15 ìpínrọ̀ 13 sí 20 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Aísáyà 38-42 (10 min.)
No. 1: Aísáyà 39:1–40:5 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ọlọ́run Kò Nífẹ̀ẹ́ Sí Àmúlùmálà Ìgbàgbọ́—td 5A (5 min.)
No. 3: Ohun Tó Mú Kí Ẹ̀kọ́ Tí Ọlọ́run Ń Kọ́ Wa Ta Yọ—Fílí. 3:8 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Ìfilọ̀. Sọ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a máa lò lóde ẹ̀rí ní oṣù February, kí o sì ṣe àṣefihàn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan tàbí méjì.
10 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ẹ ka Máàkù 10:17-30. Ẹ jíròrò bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
15 min: “Wàásù fún ‘Ènìyàn Gbogbo.’” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Jíròrò ìdí tá a fi ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé pẹlẹbẹ tá a tò sínú àfikún tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí. Lẹ́yìn náà, kó o wá yan ìwé pẹlẹbẹ méjì tó lè ṣe àwọn èèyàn láǹfààní ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Sọ̀rọ̀ nípa àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà, kó o sì ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè lò ó lóde ẹ̀rí.
Orin 112 àti Àdúrà