Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 16
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JANUARY 16
Orin 98 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 15 àpótí tó wà ní ojú ìwé 121 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Aísáyà 34-37 (10 min.)
No. 1: Aísáyà 35:1-10 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ó Yẹ Ká Fọkàn Tán Jèhófà—Sm. 25:1-5 (5 min.)
No. 3: Jèhófà Nìkan Ló Yẹ Ká Máa Jọ́sìn—td 9D (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
15 min: Fi Òye Mọ Èrò Ọkàn Ẹni Tó Béèrè Ọ̀rọ̀. Àsọyé tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 66, ìpínrọ̀ 1, sí ojú ìwé 68, ìpínrọ̀ 3. Ní ṣókí, ṣe àṣefihàn bí onílé kàn ṣe béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ akéde kan. Akéde náà wá ń dá nìkan sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣeé ṣe kó jẹ́ èrò ẹni tó béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ àti ohun tó lè máa jẹ ẹ́ lọ́kàn, lẹ́yìn náà, akéde náà wá dáhùn lọ́nà tó dára.
15 min: Ẹ Tọ́jú Ìwà Yín Kí Ó Dára Lọ́pọ̀lọpọ̀ Láàárín Àwọn Orílẹ̀-Èdè. (1 Pét. 2:12) Ìjíròrò tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ June 15, 2009, ojú ìwé 15, ìpínrọ̀ 16 àti 17, àti ojú ìwé 19, ìpínrọ̀ 14. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
Orin 97 àti Àdúrà