Máa Fi Ọgbọ́n Darí Àwọn Ẹ̀ṣẹ́ Rẹ
1. Báwo ni ọ̀rọ̀ inú 1 Kọ́ríńtì 9:26 ṣe kan iṣẹ́ ìwàásù wa?
1 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí mo ti ń sáré kì í ṣe láìní ìdánilójú; bí mo ti ń darí àwọn ẹ̀ṣẹ́ mi jẹ́ láti má ṣe máa gbá afẹ́fẹ́.” (1 Kọ́r. 9:26) Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni bí òun ṣe pọkàn pọ̀ tí ojú òun sì mú ọ̀nà kan nínú lílépa àwọn àfojúsùn tẹ̀mí tí òun ní. Àmọ́, ìlànà tó wà nínú ọ̀rọ̀ náà kan iṣẹ́ ìwàásù wa. A fẹ́ fi ọgbọ́n darí àwọn “ẹ̀ṣẹ́” wa, tàbí ìsapá wa kó lè túbọ̀ méso jáde. Báwo la ṣe lè ṣe é?
2. Báwo la ṣe lè fara wé Pọ́ọ̀lù àti àwọn míì tó jẹ́ oníwàásù ní ọ̀rúndún kìíní nípa mímọ àkókò tó yẹ ká lọ wàásù àti ibi tó yẹ ká ti wàásù?
2 Ẹ Lọ Síbi Tẹ́ Ẹ Ti Lè Rí Àwọn Èèyàn: Pọ́ọ̀lù àti àwọn míì tó jẹ́ oníwàásù ní ọ̀rúndún kìíní wàásù ní àwọn ibi tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ti máa rí àwọn èèyàn. (Ìṣe 5:42; 16:13; 17:17) Torí náà, tó bá jẹ́ pé ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń wà nílé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, a jẹ́ pé àkókò yẹn lè jẹ́ èyí tó dára jù láti wàásù láti ilé dé ilé. Ṣé àwọn èèyàn máa ń wà ní ibùdókọ̀ ní àárọ̀ kùtù nígbà tí wọ́n bá ń lọ síbi iṣẹ́ tàbí lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ nígbà tí wọ́n bá ń pa dà sílé? Ìgbà wo ni àwọn èèyàn sábà máa ń pọ̀ ní àwọn ibi ìtajà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín? Ìjẹ́rìí òpópónà lè méso jáde gan-an nírú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀.
3. Báwo la ṣe lè fi ọgbọ́n darí ẹ̀ṣẹ́ wa nípa bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ wa?
3 Ẹ Máa Fi Ọgbọ́n Ṣiṣẹ́ Ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Yín: A tún gbọ́dọ̀ kíyè sí bá a ṣe ń darí ẹ̀ṣẹ́ wa nípa bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ wa. Bí àpẹẹrẹ, dípò tá a fi máa darí gbogbo àwọn ará tó jáde òde ẹ̀rí lọ sí àgbègbè kan náà, èyí tó máa gba ọ̀pọ̀ àkókò àti ìsapá láti ṣètò bí wọ́n ṣe máa wàásù, ó máa dára pé ká ti pín wọn kí wọ́n tó lọ síbi tí wọ́n ti máa wàásù. Bákan náà, nígbà tá a bá ń ṣiṣẹ́ ní àwọn ìgbèríko, ó máa rọrùn fún wa láti tètè kárí ibi tá a ti fẹ́ ṣiṣẹ́, ó sì túbọ̀ máa rọrùn fún olúkúlùkù láti rí ẹni bá sọ̀rọ̀ tí a kò bá pọ̀ jù lójú kan. Ṣé o lè ní kí wọ́n fún ẹ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù kan tó sún mọ́ ilé rẹ, èyí tí kò ní gbà ẹ́ lákòókò púpọ̀ láti dé, dípò ti wàá fi lọ sí ibi tó jìn?
4. Kí ló máa mú ká ṣàṣeyọrí gẹ́gẹ́ bí “apẹja ènìyàn”?
4 Jésù fi àwọn tó ń wàásù wé àwọn “apẹja ènìyàn.” (Máàkù 1:17) Kì í ṣe wíwulẹ̀ ju àwọ̀n sódò ni ohun tó jẹ apẹja lógún, ohun tó jẹ ẹ́ lógún ni pé kí ó rí ẹja pa. Nítorí náà, àwọn apẹja tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ máa ń lọ síbi tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ti lè rí ẹja pa, àkókò tó tọ́ ni wọ́n máa ń lọ, wọn kì í sì í jáfara bí wọ́n bá ti dé ibẹ̀. Ńṣe ni wọ́n máa ń fi ọgbọ́n darí ìsapá wọn. Ǹjẹ́ kí àwa náà máa ṣe irú akitiyan bẹ́ẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù wa.—Héb. 6:11.