Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 9
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JANUARY 9
Orin 53 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 15 ìpínrọ̀ 8 sí 12 àti àpótí tó wà ní ojú ìwé 118 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Aísáyà 29-33 (10 min.)
No. 1: Aísáyà 30:15-26 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ohun Tí Ìjọsìn Ère Máa Ń Yọrí Sí—td 9B (5 min.)
No. 3: Báwo Ni Èèyàn Aláìpé Ṣe Lè Sọ Orúkọ Jèhófà Di Mímọ́?—Mát. 6:9 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀. Ẹ Jíròrò “Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn” tó wà ní ojú ìwé 4. Gbóríyìn fún àwọn ará fún ìsapá tí wọ́n ṣe láti jẹ́ kí ìròyìn iṣẹ́ ìsìn oṣù August dára gan-an. Fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n tètè máa fi ìròyìn wọn sílẹ̀ lóṣooṣù.
10 min: Wàásù fún Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Tó Yàtọ̀ Sí Tìrẹ. Àsọyé. Ṣàlàyé bí a ṣe lè lo ìwé kékeré náà, Good News for People of All Nations. Ṣe àṣefihàn kan.
10 min: Àwọn Ẹ̀rí Tó Fi Hàn Pé Bíbélì Ní Ìmísí Ọlọ́run. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé pẹlẹbẹ Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, ojú ìwé 10 sí 16.
10 min: “Máa Fi Ọgbọ́n Darí Àwọn Ẹ̀ṣẹ́ Rẹ.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 2, fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ní ṣókí, ní kó sọ àwọn ibi tẹ́ ẹ ti lè rí ọ̀pọ̀ èèyàn wàásù fún ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín láàárín ọ̀sẹ̀ àti àkókò tẹ́ ẹ lè rí wọn.
Orin 115 àti Àdúrà