Ṣó O Ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Tara Ẹ?
1. Kí ló ń jẹ́ ìpínlẹ̀ ìwàásù ara ẹni?
1 Ìpínlẹ̀ ìwàásù tí ìjọ bá yàn fún ẹ ní tààràtà pé kó o ti máa wàásù ló ń jẹ́ ìpínlẹ̀ ìwàásù ara ẹni. Bó bá ṣeé ṣe, kò yẹ kó jìnnà jù kó o bàa lè máa tètè débẹ̀ láti wàásù níwọ nìkan tàbí pẹ̀lú akéde mìíràn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó dáa jù ni pé kí gbogbo wa máa kọ́wọ́ ti ètò tí ìjọ bá ṣe fún ìjẹ́rìí àjẹ́pọ̀ bó bá ṣe lè ṣeé ṣe tó, bí kálukú bá ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tara ẹ̀ tó ti lè máa ṣiṣẹ́ láwọn àkókò mìíràn, ó máa mú ká lè jẹ́rìí kúnnákúnná, pàápàá bí ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ bá pọ̀ gan-an.—Ìṣe 10:42.
2. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tó wà nínú kéèyàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tara ẹ̀?
2 Àwọn Àǹfààní Tó Wà Níbẹ̀: Àwọn kan tí ìpínlẹ̀ ìwàásù tara ẹni wọn sún mọ́ ibi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ti rí i pé ó máa ń rọrùn fáwọn láti wàásù ní àkókò ìsinmi ọ̀sán tàbí gbàrà táwọn bá ṣíwọ́ iṣẹ́. Àwọn míì sì ti kíyè sí i pé ó máa ń rọrùn fún gbogbo ìdílé láti wàásù pa pọ̀ ládùúgbò wọn fún wákàtí kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ kí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tó bẹ̀rẹ̀. Bí ìpínlẹ̀ ìwàásù ara ẹni bá wà nítòsí lọ́nà yìí, ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì á wà lárọ̀ọ́wọ́tó, ìyẹn á sì dín wàhálà, àkókò àti owó tá máa ná wọn láti débẹ̀ kù. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé ìpínlẹ̀ ìwàásù tara ẹni máa ń dín àkókò téèyàn ń lò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ kù, ó lè mú nǹkan rọrùn fáwọn tó bá fẹ́ máa gbaṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóòrèkóòrè tàbí àwọn tó tiẹ̀ fẹ́ wọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Bákan náà, bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tara wa tá a sì ń dojúlùmọ̀ àwọn tó ń gbébẹ̀, wọ́n á lè mọ̀ wá dáadáa, á sì rọrùn fún wa láti lè mú ọ̀rọ̀ wa bá ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn mu, èyí á sì jẹ́ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa túbọ̀ nítumọ̀ sí wọn.
3. Kí ni aṣáájú-ọ̀nà kan tó ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tara ẹ̀ sọ?
3 Aṣáájú-ọ̀nà kan tí alábòójútó àyíká gbà níyànjú pé ó yẹ kóun náà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tara ẹ sọ pé: “Mo ṣiṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ìyànjú yẹn, kò sì pẹ́ tí mo fi dojúlùmọ̀ àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù mi tá a sì dọ̀rẹ́. Mo yí àkókò tí mo máa ń lọ sọ́dọ̀ wọn padà kó lè bá àkókò tí wọ́n máa ń wà nílé mu. Nígbà tó yá, ìpadàbẹ̀wò tí mo máa ń ṣe lóṣù di ọgọ́rin látorí márùndínlógójì, méje sì ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé tí mò ń darí.”
4. Bá a bá fẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tára wa, kí la lè ṣe, ọ̀nà wo la sì lè gbà máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀?
4 Bó O Ṣe Máa Ṣe É: Bó o bá fẹ́ láti ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tara ẹ, sọ fún ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìpínlẹ̀ ìwàásù. O lè sọ fún akéde mìíràn pé kẹ́ ẹ jọ ṣiṣẹ́, kó o sì máa ṣàkọsílẹ̀ àdírẹ́sì àwọn tẹ́ ò bá bá nílé. O gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù náà láàárín oṣù mẹ́rin. Bí kò bá rọrùn fún ẹ láti ṣe é tán, o lè bá alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ rẹ tàbí ẹlòmíì sọ ọ́ kí wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bí oṣù mẹ́rin bá ti parí, o lè dá ìpínlẹ̀ tó o ti ṣe tán náà padà tàbí kó o ní kí wọ́n jẹ́ kó o tún ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i. Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé wà á máa ṣe é títí lọ gbére o, o ní láti dá a padà káwọn ẹlòmíì lè rí i gbà. Bí ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ tó o wà ò bá pọ̀ tó, tí kò sì ṣeé ṣe láti ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tara ẹ, ó lè ní kí alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tó ò ń dara pọ̀ mọ́ fún ẹ ní díẹ̀ lára ìpínlẹ̀ ìwàásù tí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ yín ti ń ṣiṣẹ́.
5. Kí la ní láti ṣe ká bàa lè kẹ́sẹ járí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tá a gbà?
5 Iṣẹ́ tó ń gbomi mu ni iṣẹ́ tá a gbà láti máa wàásù “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mát. 24:14) Iṣẹ́ tó gbètò ni. Bá a bá ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tara ẹni pa pọ̀ pẹ̀lú ìṣètò ìjẹ́rìí àjẹ́pọ̀, a ó lè wàásù fún gbogbo ẹni tó bá ṣeé ṣe láti wàásù ìhìn rere fún.