Kí Ni Ṣíṣe Bá Ò Bá Bá Àwọn Kan Nílé?
1. Ìṣòro wo la sábà máa ń bá pàdé tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé?
1 Láwọn àdúgbò kan, ó ti wá ń ṣòro gan-an láti máa bá àwọn èèyàn nílé. Nítorí pé “àkókò lílekoko,” là ń gbé, ó ti wá ń pọn dandan fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti fi èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò wọn lóòjọ́ ṣiṣẹ́ torí kí ọwọ́ wọn bàa lè tẹ́nu. (2 Tím. 3:1) Àwọn kan lè lọ rajà tàbí kí wọ́n najú lọ. Báwo la ṣe lè rí irú àwọn ẹni yìí wàásù ìhìn rere fún?
2. Kí ló yẹ ká ṣe kí ìwàásù bàa lè dé etígbọ̀ọ́ àwọn tá ò bá bá nílé?
2 Máa Kọ Àkọsílẹ̀ Nípa Àwọn Onílé: Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ni pé ká kọ àkọsílẹ̀ nípa àwọn tá ò bá bá nílé. Èyí ṣe pàtàkì gan-an bó bá jẹ́ pé lemọ́lemọ́ là ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Ǹjẹ́ o ti kọ orúkọ òpópónà tẹ́ni náà ń gbé, nọ́ńbà ìpínlẹ̀ ìwàásù náà bó ṣe wà nínú káàdì ìpínlẹ̀ ìwàásù tó wà lọ́wọ́ ìránṣẹ́ ìpínlẹ̀, orúkọ rẹ̀ àti déètì ọjọ́ tó o wá a délé tó ò bá a? Bó o bá fẹ́, o tún lè fi àwọn ìsọfúnni mìíràn kún àkọsílẹ̀ náà bí ìwọ tàbí akéde mìíràn bá padà lọ sọ́dọ̀ àwọn tí ẹ kò bá nílé lákọ̀ọ́kọ́.
3. Àbá wo la lè tẹ̀ lé nípa àwọn tá ò bá bá nílé?
3 Padà Lọ Nígbà Míì: Ó ṣeé ṣe káwọn tí kì í sí nílé láàárín ọ̀sẹ̀ wà nílé lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ tàbí lópin ọ̀sẹ̀. Ṣó o lè tún ètò rẹ ṣe kó o bàa lè padà lọ nígbà míì tó ṣeé ṣe kó o bá wọn nílé? (1 Kọ́r. 10:24) Bí kò bá ní ṣeé ṣe fún ẹ́ láti padà lọ, o lè fa àkọsílẹ̀ ẹni tó ò bá nílé náà lé akéde kan tó máa lè lọ nígbà míì lọ́wọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, o lè kọ lẹ́tà sí ẹni náà. Àwọn akéde tí àìlera ò sì jẹ́ kí wọ́n lè wàásù láti ilé dé ilé lè fẹ́ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti padà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ò bá nílé.
4. Kí ló jẹ́ ká rí bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé ká wá àwọn tí a kì í bá nílé kàn?
4 Ohun kan ṣẹlẹ̀ tó jẹ́ ká rí bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé ká wá àwọn tí a kì í bá nílé kàn. Ìṣẹ̀lẹ̀ náà dá lórí ilé kan báyìí tó jẹ́ pé lẹ́yìn ọdún kẹta táwọn akéde kan ti ń pààrà ibẹ̀ ni wọ́n tó rí onílé náà sójú. Àṣé onílé náà ti ń wá bó ṣe máa rí Ẹlẹ́rìí Jèhófà táá wá máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ tó bẹ̀rẹ̀ kó tó kó kúrò níbi tó ń gbé nìṣó.
5. Ìgbà wo la lè sọ pé a ti ṣe ìpínlẹ̀ ìwàásù kan tán?
5 Ẹ Rí I Pé Ẹ Ṣe Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Yín Tán: Ìgbà wo la tó lè sọ pé a ti ṣe ìpínlẹ̀ ìwàásù kan tán? Ó sábà máa ń jẹ́ nígbà tá a bá ti sapá láti rí gbogbo àwọn tó wà nílé kọ̀ọ̀kan tó wà nírú ìpínlẹ̀ bẹ́ẹ̀ bá sọ̀rọ̀. Bó bá jẹ́ pé ohun tó bójú mu ni ládùúgbò náà, a lè fi ìwé àṣàrò kúkúrú tàbí ìwé ìròyìn tó ti pẹ́ síbi tó yẹ ní ilé tá ò bá ti bá àwọn tó ń gbébẹ̀, àgàgà bó bá jẹ́ ìpínlẹ̀ ìwàásù tí a kì í ṣe déédéé ni. Bá a bá sì ti ṣe é tán ni ká ti yáa fi tó ìránṣẹ́ ìpínlẹ̀ ìwàásù létí kó bàa lè fi kún àkọsílẹ̀ rẹ̀.
6. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti jẹ́ kí gbogbo ẹni tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa gbọ́ ìhìn rere?
6 A fẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti láǹfààní mímọ bí wọ́n ṣe lè pe orúkọ Jèhófà kí wọ́n bàa lè ní ìgbàlà. (Róòmù 10:13, 14) Àwọn tá ò bá bá nílé nígbà tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé náà wà lára ọ̀pọ̀ èèyàn tó yẹ kó rí ìgbàlà. Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, fi sọ́kàn pé o ní “láti jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.”—Ìṣe 20:24.