Ṣé Ìjọ Yín Ní Ìpínlẹ̀ Tó Tóbi Gan-an?
1 Jésù jẹ́rìí kúnnákúnná jákèjádò àwọn ìpínlẹ̀ títóbi ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un, láti àwọn ìlú ńlá tó wà nílẹ̀ Jùdíà títí lọ dé àwọn ìgbèríko ilẹ̀ Gálílì. (Máàkù 1:38, 39; Lúùkù 23:5) Àwa náà gbọ́dọ̀ wàásù ìhìn rere náà fún gbogbo ènìyàn tó bá ṣeé ṣe fún wa láti rí. (Máàkù 13:10) Àmọ́ o, èyí lè má rọrùn. Kí nìdí?
2 Ọ̀pọ̀ ìjọ ní Nàìjíríà ló jẹ́ pé ìgbèríko ni èyí tó pọ̀ jù lọ lára ìpínlẹ̀ wọn wà, wọ́n sì máa ń fẹ̀ tó ọ̀pọ̀ kìlómítà. Kí la lè ṣe láti ṣèrànwọ́ fún àwọn èèyàn tó ń gbé ní irú àwọn ìpínlẹ̀ tó lọ salalu bẹ́ẹ̀ kí wọ́n bàa lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Jèhófà, Jésù àti Ìjọba náà?
3 Ẹ Fara Balẹ̀ Ṣètò Iṣẹ́ Ìsìn Pápá: Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn àti ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìpínlẹ̀ ní láti darí ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá kí ìjọ lè kẹ́sẹ járí. Bóyá ẹ lè ṣètò àwọn ọjọ́ Sátidé kan lákànṣe, nígbà tó máa ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará láti ṣiṣẹ́ fún odindi ọjọ́ kan gbáko. Nígbà tẹ́ ẹ bá lọ wàásù láwọn ìpínlẹ̀ tó jìnnà, tó bá ṣeé ṣe kí ẹ ṣètò láti lo àkókò púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, kí ẹ sì gbé oúnjẹ tẹ́ ẹ máa jẹ lọ́sàn-án dání. Ẹ lè jẹ́ kí àkókò tẹ́ ẹ máa pàdé fún iṣẹ́ ìsìn yá ju ti tẹ́lẹ̀ lọ kí ẹ lè ní àkókò tó pọ̀ tó láti dé ìpínlẹ̀ náà tàbí kẹ́ ẹ lọ ṣe ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá lẹ́bàá ibi tẹ́ ẹ ti máa ṣiṣẹ́. Ẹ jẹ́ kí àwọn akéde tẹ́ ẹ máa pín sójú kan mọ níwọ̀n kí gbogbo wọn lè ríṣẹ́ ṣe dáadáa. Ẹ ṣètò láti ṣe àwọn àgbègbè ìgbèríko láwọn àkókò tí ojú ọjọ́ bá bára dé tí ojú ọ̀nà á sì ṣeé rìn. Ẹ ṣètò àwọn ìpínlẹ̀ lọ́nà tó máa fi ṣeé ṣe fún àwọn tí wọ́n bá pín sí àgbègbè kan láti dé gbogbo ilé tó wà níbẹ̀.
4 Ẹ rí i pé ẹ kó ìwé tó pọ̀ tó dání. Tó bá jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan lẹ máa ń ṣe ìpínlẹ̀ náà, á dáa kẹ́ ẹ fi ìwé àṣàrò kúkúrú tàbí àwọn ìwé ìròyìn tọ́jọ́ wọn ti pẹ́ sílẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà àwọn tí kò bá sí nílé.
5 Ẹ Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ ní Kíkún: Jíjẹ́rìí láwọn ìpínlẹ̀ títóbi ń béèrè pé kí gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Tó bá gba pé kí ẹ gbé mọ́tò lọ sírú ibi tó jìnnà bẹ́ẹ̀, ẹ lè pín owó epo tí ọkọ̀ máa lò san. Kí ẹ lo òye nígbà tí ẹ bá pàdé àwọn onílé tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìjíròrò Bíbélì. Ẹ ní in lọ́kàn pé gbogbo àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ náà lẹ fẹ́ wàásù fún. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnikẹ́ni fẹ́ máa bá ìjíròrò lọ pẹ̀lú ẹnì kan tó fìfẹ́ hàn, ó kúkú lè ṣètò fún ìpadàbẹ̀wò lẹ́yìn tó bá ti ṣe ìpínlẹ̀ tí a yàn fún un tán?
6 Ṣe ètò tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ láti padà bẹ gbogbo àwọn tó fìfẹ́ hàn wò. Yàtọ̀ sí àdírẹ́sì olùfìfẹ́hàn kan, gbìyànjú láti gba nọ́ńbà tẹlifóònù rẹ̀ kó o lè kàn sí i, kó o sì lè túbọ̀ jẹ́rìí fún un lórí tẹlifóònù. Bí àwọn ọ̀nà ìgbèríko kò bá ní orúkọ tàbí bí àwọn ilé kò bá ní nọ́ńbà, fara balẹ̀ kọ àpèjúwe olùfìfẹ́hàn náà sílẹ̀ nípa bó o ṣe lè rí i nígbà ìpadàbẹ̀wò.
7 Àǹfààní ńlá la mà ní o láti ṣègbọràn sí àṣẹ tí Jésù pa pé: “Ìlú ńlá tàbí abúlé èyíkéyìí tí ẹ bá wọ̀, ẹ wá ẹni yíyẹ inú rẹ̀ kàn”! (Mát. 10:11) Ó dájú pé Jèhófà yóò bù kún akitiyan yin bẹ́ ẹ ti ń fi tinútinú yọ̀ǹda ara yín nínú iṣẹ́ tó lérè jù lọ yìí!