Àkànṣe Ìgbòkègbodò Tá A Ó Ṣe Láàárín February 19 sí March 18!
1 A ti ń pín ìwé àṣàrò kúkúrú Kingdom News No. 37 tó ni àkọlé náà “Òpin Ìsìn Èké Sún Mọ́lé!” káàkiri ayé báyìí. Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà la o lò láwọn ọ̀sẹ̀ méjì àkọ́kọ́ lóṣù February. Láti Monday, February 19, títí di Sunday, March 18, a óò pín ìwé àṣàrò kúkúrú Kingdom News No. 37 jákèjádò ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Láwọn òpin ọ̀sẹ̀, a óò tún máa lo àwọn ìwé ìròyìn láfikún sí pípín ìwé àṣàrò kúkúrú náà.
2 Àwọn Wo Ni Kó Lọ́wọ́ sí Pípín Ìwé Náà: A mọ̀ pé gbogbo àwọn akéde tó ti n fì ìtara wàásù ìhìn rere náà ló máa fẹ́ ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ láti ṣe kí wọ́n bàa lè pín ìwé àṣàrò kúkúrú náà. Àwọn mìíràn tiẹ̀ lè gba aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ láàárín àkókò yìí. Ǹjẹ́ o láwọn ọmọ tàbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó o kíyè sí pé ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn ń lọ déédéé tí wọ́n sì ń wá sípàdé? Rí i pé ọmọ náà tàbí akẹ́kọ̀ọ́ tó fẹ́ máa wàásù sọ fáwọn alàgbà, kí wọ́n bàa lè gbé wọn yẹ̀ wò bóyá wọ́n yẹ lẹ́ni tó lè máa sìn gẹ́gẹ́ bí akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Ẹ̀yin alàgbà fúnra yín ni kẹ́ ẹ tọ àwọn akéde aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ, kẹ́ ẹ sì gbà wọ́n níyànjú láti lọ́wọ́ sí àkànṣe ìgbòkègbodò náà, ẹ lè ní kí wọ́n bá àwọn akéde tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ṣiṣẹ́ pọ̀.
3 A ti fi ẹ̀dà Kingdom News No. 37 tó pọ̀ tó ránṣẹ́ sí gbogbo ìjọ, kí akéde kọ̀ọ̀kan àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà gba àádọ́ta ẹ̀dà ìwé yìí. Àwọn olùfìfẹ́hàn tí ò tíì ṣèrìbọmi le gba ẹ̀dà márùn-ún kí wọ́n sì fún àwọn mọ̀lẹ́bí àti ọ̀rẹ́ wọn. Kí aṣáájú-ọ̀nà àtàwọn akéde kọ iye tí wọ́n bá pín sẹ́yìn fọ́ọ̀mù tí wọ́n bá fi ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù February àti March. Akọ̀wé á wá ro iye ẹ̀dà tí gbogbo ìjọ pín ní oṣù kan pọ̀, á sì fi í ṣọwọ́ si ẹ̀ka iléeṣẹ́, kó sì ṣe bẹ́ẹ̀ lóṣù méjèèjì. Ẹ lè lo ẹ̀dà ìwé àṣàrò kúkúrú Kingdom News No. 37 tó bá ṣẹ́ kù lẹ́yìn tí ìpínkiri náà bá ti parí nínú ìwàásù ilé-dé-ilé tàbí láwọn ọ̀nà mìíràn.
4 Ohun Tó O Lè Sọ: Kó bàa lè ṣeé ṣe láti pín ìwé àṣàrò kúkúrú náà kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín láàárín àkókò kúkúrú, ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tẹ́ ẹ máa sọ mọ níwọ̀n. O kan lè sọ pè: “Oníwàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni mí, mo wà lára àwọn tó ń pín ìwé àṣàrò kúkúrú kan tí ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ṣe pàtàkì. Kárí ayé là ń pín ìwé àṣàrò kúkúrú náà. Ọ̀fẹ́ ni màá fún ẹ. Jọ̀wọ́, rí i pé o kà á.” Kó o sì kọ orúkọ àti àdírẹ́sì ẹni tó bá gbà á tó sì ní kẹ́ ẹ padà wá sílẹ̀.
5 Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Kárí Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Yín: Wíwàásù fáwọn èèyàn láti ilé dé ilé àti láwọn ibi okòwò wọn ni kẹ́ ẹ gbájú mọ́ dípò pípín ìwé àṣàrò kúkúrú Kingdom News No. 37 ní òpópónà. Kọ àdírẹ́sì gbogbo àwọn tí kò bá sí nílé, kó o sì wá padà lọ láwọn ọjọ́ àti àkókò mìíràn láàárín ọ̀sẹ̀. Láti Monday, March 12, ẹ lè bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìwé àṣàrò kúkúrú náà há ẹnu ọ̀nà àwọn tí kò bá sí nílé. Àmọ́ bó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ìpínlẹ̀ ìwàásù yín pọ̀ ju èyí tẹ́ ẹ lè kárí láàárín àkókò tá a ṣètò fún ìpínkiri náà, àwọn alàgbà le pinnu pé káwọn ará máa fi ìwé àṣàrò kúkúrú náà há ẹnu ọ̀nà àwọn tí kò bá sí nílé jálẹ̀ àkànṣe ìgbòkègbodò náà.
6 Bí ìparun “Bábílónì Ńlá” ti ń sún mọ́lé ju ti ìgbàkígbà rí lọ, àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ jáde kúrò nínú ẹ̀ kó tó kàgbákò ìparun. (Ìṣí. 14:8; 18:8) Tètè bẹ̀rẹ̀ sí í gbára dì kó o lè kópa tó jọjú nínú àkànṣe ìgbòkègbodò tó máa kárí ayé yìí, kó bàa lè ṣeé ṣe fún gbogbo èèyàn láti mọ̀ pé òpin ìsìn èké ti sún mọ́lé!