ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/08 ojú ìwé 6-7
  • A Máa Pín Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Lákànṣe ní January 19 sí February 15, 2009!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Máa Pín Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Lákànṣe ní January 19 sí February 15, 2009!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àkànṣe Ìgbòkègbodò Tá A Ó Ṣe Láàárín February 19 sí March 18!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Máa Lò Ó Nígbà Gbogbo
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Pín Ìròyìn Ìjọba No. 35 Kiri Lọ́nà Gbígbòòrò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • “Mìlẹ́níọ̀mù Tuntun—Kí Ni Ká Máa Retí?”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 12/08 ojú ìwé 6-7

A Máa Pín Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Lákànṣe ní January 19 sí February 15, 2009!

1 Fún ọ̀sẹ̀ mẹ́rin gbáko, bẹ̀rẹ̀ láti Monday January 19, 2009, a máa pín ìwé àṣàrò kúkúrú tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe lákànṣe, àkọlé àṣàrò kúkúrú náà ni Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? Ìrètí wa ni pé àkànṣe ìpolongo yìí máa jẹ́ káwọn èèyàn túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí orísun òtítọ́ kan ṣoṣo náà.—Jòh. 17:17.

2 Ìwé àṣàrò kúkúrú yìí dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì mẹ́fà látinú Bíbélì lọ́nà tó sojú abẹ níkòó, àwọn ìbéèrè náà ni: “Ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run bìkítà nípa wa?” “Ṣé ogun àti ìjìyà máa dópin?” “Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tá a bá kú?” “Ṣé ìrètí kankan tiẹ̀ wà fáwọn tó ti kú?” “Báwo ni mo ṣe lè gbàdúrà tí Ọlọ́run á sì gbọ́ àdúrà mi?” àti “Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ aláyọ̀?” Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí lọ́nà tó tẹ́ni lọ́rùn rí. Kódà, àwọn tí kì í ṣe Kristẹni pàápàá ti ń wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn, àmọ́ wọ́n lè má mọ̀ pé àwọn ìdáhùn tó ṣe kedere wà nínú Bíbélì. Ìdí nìyẹn tá a fi nírètí pé ìwé àṣàrò kúkúrú yìí á fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra.

3 Ẹ Kárí Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Yín: Ẹ gbìyànjú láti kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín nípa wíwàásù láti ilé délé. Bí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín bá tóbi, àwọn alàgbà lè sọ pé kẹ́ ẹ máa fi ìwé àṣàrò kúkúrú náà há ẹnu ọ̀nà àwọn tẹ́ ò bá bá nílé nígbà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ bá débẹ̀. Ẹ má gbàgbé láti fún àwọn aládùúgbò, àwọn mọ̀lẹ́bí, àwọn ojúlùmọ̀ yín níbi iṣẹ́ tàbí níléèwé àtàwọn míì tẹ́ ẹ sábà máa ń bá sọ̀rọ̀ ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà. Bó bá ṣeé ṣe, ẹ lè ṣètò láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù January tàbí February 2009. Ṣé ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ tàbí àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti lóye òtítọ́ débi tó fi lè dara pọ̀ mọ́ wa láti pín ìwé àṣàrò kúkúrú yìí gẹ́gẹ́ bí akéde tí ò tíì ṣèrìbọmi? Bó bá wà, sọ fáwọn alàgbà.

4 Ohun Tẹ́ Ẹ Máa Sọ: Ohun tó máa dáa jù ni pé ká má ṣe jẹ́ kọ́rọ̀ wa gùn jù, ká lè dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tó pọ̀. Ẹ lè bi àwọn tẹ́ ẹ bá bá pàdé ní ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè mẹ́fà tó wà níwájú ìwé àṣàrò kúkúrú náà, kẹ́ ẹ sì fi ìdáhùn hàn wọ́n nínú rẹ̀. Èyí á jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn akéde láti jẹ́ kọ́rọ̀ wọn bá ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ládùúgbò wọn mu. Bẹ́ ẹ bá rí i pé ẹnìkan nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ tẹ́ ẹ bá a sọ, ẹ kọ orúkọ onítọ̀hún àti àdírẹ́sì rẹ̀, kẹ́ ẹ sì pa dà bẹ̀ ẹ́ wò. Lópin ọ̀sẹ̀, ẹ lè lo àwọn ìwé ìròyìn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé lóde ẹ̀rí pa pọ̀ pẹ̀lú ìwé àṣàrò kúkúrú náà. Lẹ́yìn tí ìpolongo yìí bá parí ní February 15, ìwé Sún Mọ́ Jèhófà la máa bẹ̀rẹ̀ sí í lò lóde ẹ̀rí. Bá a ṣe ń lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú wa míì náà la ṣe máa lo èyí tó bá kù lára ìwé àṣàrò kúkúrú yìí.

5 Ẹ Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: A ṣe ìwé àṣàrò kúkúrú yìí lọ́nà tó máa jẹ́ kó rọrùn fún wa láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tẹ́ ẹ bá pa dà bẹ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa wò, ẹ lè bi wọ́n pé èwo nínú àwọn òtítọ́ Bíbélì náà ló tù wọ́n nínú tàbí tó tù wọ́n lára jù lọ. Fi ojú ìwé tó gbẹ̀yìn hàn wọ́n níbi tá a ti ṣàlàyé bá a ṣe máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o sì fún wọn ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni. Bó bá ṣeé ṣe, ẹ lè jọ jíròrò ìpínrọ̀ kan tàbí méjì nínú orí tó túbọ̀ ṣàlàyé kókó tí onílé nífẹ̀ẹ́ sí nígbà tó ka ìwé àṣàrò kúkúrú náà látinú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni.

6 Àwọn tó máa jọ́sìn Jèhófà “ní ẹ̀mí àti òtítọ́” ni Jèhófà ń wá. (Jòh. 4:23) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa lọ́wọ́ nínú ìpolongo pàtàkì yìí láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ òtítọ́!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́