Máa Lò Ó Nígbà Gbogbo
1. Kí nìdí tá a fi ṣe ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?
1 Ńṣe la dìídì ṣe ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? ká lè máa fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, ó tún jẹ́ irinṣẹ́ tó wúlò gan-an láti fún irúgbìn òtítọ́. (Oníw. 11:6) Àwọn àbá díẹ̀ rèé nípa bá a ṣe lè lò ó lọ́nà tó gbéṣẹ́.
2. Báwo la ṣe lè fi ìwé àṣàrò kúkúrú náà bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò?
2 A Lè Fi Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò: O lè fún onílé ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, kó o wá fi àwọn ìbéèrè mẹ́fà tó wà ní iwájú ìwé náà hàn án, kó o sì béèrè pé: “Èwo lára àwọn ìbéèrè yìí ló wù ẹ́ pé kó o rí ìdáhùn sí?” Lẹ́yìn tó bá ti dáhùn, ṣí ìwé àṣàrò kúkúrú náà, kó o sì jíròrò ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè tí ẹni náà béèrè, kó o sì ka ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀. O lè ka àwọn ìpínrọ̀ tó wà lẹ́yìn ìwé náà tàbí kó o sọ àwọn kókó pàtàkì tó wà níbẹ̀ fún un, kó o wá béèrè bóyá ó nífẹ̀ẹ́ sí ìwé Kí Ni Bíbélì fi Kọ́ni Gan-an? Bí kò bá tiẹ̀ gba ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, ìwé àṣàrò kúkúrú tó gbà yẹn náà lè mú kí òtítọ́ fìdí múlẹ̀ lọ́kàn rẹ̀.—Mát. 13:23.
3. Bí ọwọ́ ẹni tá a fẹ́ wàásù fún bá dí, kí la lè ṣe?
3 Bí Ọwọ́ Ẹni Tá A Fẹ́ Wàásù fún Bá Dí: O lè sọ pé: “Mo rí i pé ọwọ́ rẹ dí báyìí, torí náà, màá fún ẹ ní ìwé yìí. Ìbéèrè mẹ́fà kan wà níbẹ̀ tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwa èèyàn ti béèrè rí, ó sì ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìbéèrè náà. Màá pa dà wá nígbà míì, kí n lè mọ èrò rẹ nípa àwọn ìbéèrè náà.”
4. Kí la lè sọ tá a bá fẹ́ lo ìwé náà nígbà ìjẹ́rìí òpópónà?
4 Tá A Bá Ń Ṣe Ìjẹ́rìí Òpópónà: Lẹ́yìn tó o bá ti kí onítọ̀hún, o lè sọ pé: “Ǹjẹ́ o ti béèrè èyíkéyìí lára àwọn ìbéèrè yìí rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé yìí sọ àwọn ìdáhùn tó fini lọ́kàn balẹ̀ tí Bíbélì fúnni lórí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.” Bí ẹni náà kò bá kánjú, o lè jíròrò ọkàn lára àwọn ìdáhùn tó wà nínú àṣàrò kúkúrú náà pẹ̀lú rẹ̀, kó o sì béèrè bóyá ó máa fẹ́ gba ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni.
5. Báwo la ṣe lè lo ìwé àṣàrò kúkúrú náà nígbà tí a ò bá bá àwọn èèyàn nílé?
5 Àwọn Tí A Kò Bá Nílé: Láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù kan, àwọn ará sábà máa ń fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ fún àwọn tí kò bá sí nílé, níbi tí àwọn tó ń kọjá lọ kò ti ní rí i. Tó bá jẹ́ pé bẹ́ ẹ ṣe máa ń ṣe ní ìjọ yín nìyẹn, ẹ lè máa fi ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? sílẹ̀ fún àwọn tí kò bá sí nílé. Tó o bá pa dà lọ síbẹ̀, o lè sọ pé: “A ti wá síbí tẹ́lẹ̀, a ò bá yín nílé, a wá fi ìwé yìí sẹ́nu ilẹ̀kùn yín. Èwo ló wù ẹ́ pé kó o rí ìdáhùn sí lára àwọn ìbéèrè yìí?”
6. Kí ló mú kí ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? jẹ́ irinṣẹ́ tó wúlò gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
6 Ọ̀nà tó lè tètè yéni, tó sì ṣe tààràtà ni ìwé àṣàrò kúkúrú náà gbà ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì. Ohun tó wà níbẹ̀ ṣàǹfààní fún àwọn tó ń ṣe onírúurú ẹ̀sìn àtàwọn tó wá látinú àṣà ìbílẹ̀ tó yàtọ̀ síra. Ó rọrùn láti fi wàásù; kódà, àwọn ọmọdé àtàwọn akéde tuntun lè lò ó. Ǹjẹ́ o máa ń lò ó láwọn àkókò tó bá yẹ?