ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/02 ojú ìwé 3-4
  • A Ti Ní Irinṣẹ́ Tuntun fún Bíbẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Ti Ní Irinṣẹ́ Tuntun fún Bíbẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Lò Ó Nígbà Gbogbo
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Lo Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Máa Múra Tán Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 8/02 ojú ìwé 3-4

A Ti Ní Irinṣẹ́ Tuntun fún Bíbẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́!

1 Kátólíìkì paraku ni obìnrin ará Amẹ́ríkà náà. Tinútinú rẹ̀ ló fi máa ń gbèjà àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì náà. Kódà, ó tiẹ̀ ti rìnrìn àjò mímọ́ lọ sí ibùjókòó ìjọba Póòpù ní ìlú Róòmù. Síbẹ̀, nígbà tí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn sí i nílé rẹ̀, ó gbà kí wọ́n wá máa bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé. Kí nìdí tó fi gbà? Nítorí pé ó fẹ́ mọ ohun tí Bíbélì sọ, ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ kò sì ní ètò fún kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé wọn. Ẹ̀kọ́ wo ni ìrírí yìí kọ́ wa? Pé a kò mọ ẹni tó ṣeé ṣe kó tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí à ń ṣe lọ́fẹ̀ẹ́.—Oníw. 11:6.

2 Ǹjẹ́ o ti lọ́ tìkọ̀ rí láti sọ fún àwọn èèyàn pé a máa ń yọ̀ọ̀da ara wa láti kọ́ ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì lẹ́kọ̀ọ́? Ṣé gbogbo àwọn tó wà lágbègbè rẹ ló mọ̀ pé à ń ṣe èyí fún àwọn èèyàn lọ́fẹ̀ẹ́? Báwo la ṣe lè rí i dájú pé wọ́n mọ̀? Nípa lílo irinṣẹ́ tuntun kan ni! Irinṣẹ́ náà ni ìwé àṣàrò kúkúrú fífani mọ́ra kan tí ó jẹ́ olójú ewé mẹ́fà, èyí tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì? Ẹ jẹ́ ká dojúlùmọ̀ àwọn ohun tó wà nínú ìwé àṣàrò kúkúrú yìí ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí.

3 “Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kí A Ka Bíbélì?” Àwọn ìdí tó fi yẹ ká ka Bíbélì, gẹ́gẹ́ bí ìwé àṣàrò kúkúrú náà ti ṣàlàyé, fani mọ́ra gan an. Ó ṣàlàyé pé “àwọn ìtọ́ni onífẹ̀ẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run” ló wà nínú Bíbélì, tó ń fi hàn bí a ṣe lè tọ̀ ọ́ lọ nínú àdúrà fún ìrànlọ́wọ́, àti bí a ṣe lè gba ẹ̀bùn ìyè ayérayé tó ṣèlérí. (1 Tẹs. 2:13) Ìwé àṣàrò kúkúrú náà tọ́ka sí onírúurú “òótọ́ tó ń fúnni lóye” tó wà nínú Bíbélì, irú bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn téèyàn bá kú àti ìdí tí wàhálà fi gbayé kan. Ó sọ nípa “àwọn ìlànà tí Ọlọ́run fún wa nínú Bíbélì,” èyí tó jẹ́ pé tá a bá mú wọn lò, yóò ṣe ara wa lóore yóò sì tún mú ká ní ayọ̀, ìrètí àtàwọn ànímọ́ dáradára mìíràn. Ìwé àṣàrò kúkúrú náà tún pe àfiyèsí sí ìdí pàtàkì kan tó fi yẹ ká máa ka Bíbélì, ìyẹn ni, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú rẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la, èyí tó ń fi ohun tó máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ hàn wá.—Ìṣí. 21:3, 4.

4 “Ìrànlọ́wọ́ Láti Lóye Bíbélì”: Ìwé àṣàrò kúkúrú náà sọ pé: “Gbogbo wa pátá la nílò ìrànlọ́wọ́ láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Lẹ́yìn náà ló wá ṣàlàyé ọ̀nà tá a máa ń gbà kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sọ pé: “Ohun tó dára jù ni pé kéèyàn bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì látorí àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ kí ó sì máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ ní wẹ́rẹ́ wẹ́rẹ́.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé àṣàrò kúkúrú náà sọ gbangba pé “ohun tí Bíbélì bá sọ ni abẹ gé,” ó tún dìídì dárúkọ ìwé pẹlẹbẹ Béèrè gẹ́gẹ́ bí ohun tó máa ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ “láti lóye ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ lórí àwọn ẹ̀kọ́ lóríṣiríṣi.” Ìsọ̀rí tó tẹ̀ lé e wá béèrè ìbéèrè kan tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀.

5 “Ṣé O Ṣe Tán Láti Fàkókò Sílẹ̀ Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ Kó O Lè Lóye Bíbélì?” Ìwé àṣàrò kúkúrú náà ṣàlàyé pé a lè ṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà sí àkókò kan pàtó àti sí ibi tó máa rọ akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́rùn, bóyá nínú ilé rẹ̀ tàbí lórí tẹlifóònù pàápàá. Àwọn wo ló lè dara pọ̀ nínú ìjíròrò náà? Ìwé àṣàrò kúkúrú náà dáhùn pé: “Gbogbo ìdílé rẹ. Ọ̀rẹ́ rẹ èyíkéyìí tóo bá fẹ́ láti ké sí náà lè wà níbẹ̀. Bó bá sì jẹ́ pé ìwọ nìkan lo fẹ́ kí wọ́n máa bá jíròrò, dáadáa náà ni.” Báwo ni àkókò tí èèyàn máa fi kọ́ ẹ̀kọ́ náà ṣe gbọ́dọ̀ gùn tó? Ó ṣàlàyé pé: “Wákàtí kan lọ̀pọ̀ máa ń yà sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Yálà àyè rẹ̀ yọ fún ọ láti lò jù bẹ́ẹ̀ lọ tàbí o kò ní lè lò tó bẹ́ẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí ti múra tán láti ràn ọ́ lọ́wọ́.” Kókó náà gan-an nìyẹn! A ṣe tán láti mú ara wa bá ipò akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan mu.

6 “A Pè Ọ́ Láti Wá Kẹ́kọ̀ọ́”: Fọ́ọ̀mù kan wà lẹ́yìn ìwé àṣàrò kúkúrú náà tí ẹni tó gbà á lè lò láti fi béèrè fún ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí láti sọ pé kí a kàn sí òun láti ṣàlàyé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé tí à ń ṣe fún àwọn èèyàn lọ́fẹ̀ẹ́. Rekete ni àwòrán iwájú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè fara hàn níbẹ̀. Ǹjẹ́ ìwọ náà kò rí ìdí tí ìwé àṣàrò kúkúrú yìí fi máa ṣèrànwọ́ fún àwọn olóòótọ́ ọkàn púpọ̀ sí i láti tẹ́wọ́ gba ìrànwọ́ wa? Báwo la ṣe wá lè lo irinṣẹ́ tuntun yìí lọ́nà tó dára jù lọ?

7 Àwọn Wo Lo Lè Fi Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Náà Lọ̀? A lè fi lé àwọn èèyàn lọ́wọ́ tàbí ká fi sílẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà àwọn kò-sí-nílé. A lè pín in láti ilé dé ilé, ní òpópó ọ̀nà àti láwọn ibi ìtajà. Fi fún àwọn èèyàn, yálà wọ́n gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa o tàbí wọn ò gbà á. Fi sí àárín àwọn ìwé ìròyìn tàbí àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tó o fẹ́ fi sóde. Nígbà tó o bá ń kọ lẹ́tà, fi sínú àpòòwé náà. Sọ fún àwọn tó o máa ń wàásù fún nípasẹ̀ tẹlifóònù pé wàá fi ránṣẹ́ sí wọn. Rí i pé o máa ń ní àwọn ẹ̀dà lọ́wọ́ nígbà tó o bá ń lọ rajà, nígbà tó o bá wà nínú ọkọ̀ èrò, àti nígbà tó o bá ń wàásù lọ́nà tí kì í ṣe bí àṣà. Fún ẹnikẹ́ni tó bá wá sí ilé rẹ. Fún àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ, àwọn aládùúgbò rẹ, àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ, àwọn ọmọléèwé ẹlẹgbẹ́ rẹ, àtàwọn ẹlòmíràn tó o mọ̀. Gbìyànjú láti rí i pé gbogbo ẹni tí ò ń bá pàdé pátá lo fún! Lẹ́yìn ìyẹn ńkọ́?

8 Bó Bá Jẹ́ Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ Lẹni Náà Fi Ìfẹ́ Hàn: Kíá làwọn èèyàn kan ti máa fìfẹ́ hàn nípa sísọ pé àwọn á fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nítorí náà, nígbàkigbà tó o bá ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù, rí i dájú pé ìgbà gbogbo lo máa ń ní ẹ̀dà méjì ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọ́wọ́, ọ̀kan fún akẹ́kọ̀ọ́ náà àti ọ̀kan fún ara rẹ. Bí ẹni náà bá fẹ́, bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lójú ẹsẹ̀ níbẹ̀, láìfi àkókò ṣòfò. Ṣí ìwé pẹlẹbẹ náà sí ojú ewé àkọ́kọ́, kó o sì ka ìsọ̀rí náà, “Bí A Óò Ṣe Lo Ìwé Pẹlẹbẹ Yìí” fún un. Lẹ́yìn náà lọ sí ẹ̀kọ́ 1 ní tààràtà, kó o sì fi bí a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà hàn án. Ǹjẹ́ ẹ ò rí i pé ìgbékalẹ̀ yìí rọrùn púpọ̀?

9 Bí Olùgbọ́ Rẹ Bá Ṣì Fẹ́ Ronú Lé E Lórí Ná: Kó tóó pẹ́ jù, gbìyànjú láti padà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Nígbà tó o bá ń lọ, rí i dájú pé o ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọ́wọ́. Fi ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn kókó ẹ̀kọ́ inú ìwé pẹlẹbẹ náà hàn án ní ojú ewé àkọ́kọ́. Jẹ́ kó yan kókó ẹ̀kọ́ tó fà á mọ́ra jù lọ. Ṣí i sí ibẹ̀, kẹ́ ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí í jíròrò ẹ̀kọ́ tó mú náà.

10 Pípadà Lọ Sọ́dọ̀ Àwọn Tó Gba Ìwé Ìròyìn: Bó o bá fi ìwé àṣàrò kúkúrú náà sóde pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìwé ìròyìn kan, o lè lo ìgbékalẹ̀ yìí nígbà tó o bá padà débẹ̀: “Nígbà tí mo wá kẹ́yìn, mo láyọ̀ láti fi ẹ̀dà kan ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sílẹ̀ fún ọ. Ó ṣeé ṣe kí o ti rí i pé ohun tí àkòrí ìwé àtìgbàdégbà wa náà sọ ní kíkún ni, Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà. Lónìí, màá fẹ́ láti ṣàlàyé ohun tí Ìjọba yìí jẹ́ àtohun tí yóò ṣe fún ìwọ àti ìdílé rẹ.” Lẹ́yìn náà, ṣí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè sí ẹ̀kọ́ 6. Nípa bíbẹ̀rẹ̀ ní ìpínrọ̀ kìíní, ka àwọn ìpínrọ̀ náà lọ́kọ̀ọ̀kan, kó o sì jíròrò wọn bí onílé náà bá ṣe fàyè sílẹ̀ tó. Lẹ́yìn náà ṣètò láti padà wá ní ọjọ́ mìíràn láti wá parí ìyókù ẹ̀kọ́ náà.

11 Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Náà Máa Tán Lọ́wọ́ Rẹ: Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn àtàwọn arákùnrin tó ń bójú tó ìwé yóò máa rí sí i pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Mọ Bíbélì ń wà lọ́wọ́ nígbà gbogbo, nínú ìjọ. Máa ní àwọn ẹ̀dà bíi mélòó kan nínú àpò tàbí àpamọ́wọ́ rẹ, nínú mọ́tò rẹ, ní ibi iṣẹ́ rẹ, ní iléèwé, lẹ́nu ọ̀nà àbáwọlé rẹ—níbikíbi tí ọwọ́ ṣáà ti máa tètè tó wọn. Láìsí pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń sọ ọ́, ó yẹ kó o máa kó díẹ̀ sínú àpò ìwàásù rẹ nítorí àwọn ìgbà tí wàá bá ẹnì kan tó o lè bá jíròrò Bíbélì pàdé.

12 A Gbàdúrà Kí Jèhófà Bù Kún Ìsapá Wa: Ohun dídára kan tí gbogbo Kristẹni máa ń lépa rẹ̀ ni fífi òtítọ́ kọ́ ẹlòmíràn. (Mát. 28:19, 20) Ṣé o ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé tó ò ń bá ẹnì kan ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé o lè wá àyè nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ láti fi ọ̀kan kún un? Bí o kò bá tíì máa kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní lọ́wọ́lọ́wọ́, ó dájú pé á wù ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó bù kún ìsapá rẹ láti rí ẹnì kan tí wàá máa bá kẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn náà, ṣiṣẹ́ níbàámu pẹ̀lú àdúrà rẹ.—1 Jòh. 5:14, 15.

13 Láìsí àní-àní, a ti ní irinṣẹ́ tuntun fún bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́! Mọ ohun tó wà nínú rẹ̀ dáadáa. Fún gbogbo àwọn tó o bá bá pàdé. Ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe “láti máa ṣe rere, láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà, láti jẹ́ aláìṣahun, kí [o sì] múra tán láti ṣe àjọpín” àwọn ohun tó o ti kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—1 Tím. 6:18.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]

ÀWỌN Ọ̀NÀ TÁ A LÈ GBÀ PÍN ÌWÉ ÀṢÀRÒ KÚKÚRÚ NÁÀ

◼ Nínú ìjíròrò wa ojoojúmọ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn

◼ Nígbà tí ẹnì kan bá gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa

◼ Nígbà tí a kò bá bá ẹnì kankan nílé

◼ Nígbà tá a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò

◼ Nígbà tá a bá bá ẹnì kan pàdé nínú ìjẹ́rìí òpópónà

◼ Nígbà tá a bá ń wàásù láwọn ibi ìtajà

◼ Nígbà tá a bá ń wàásù lọ́nà tí kì í ṣe bí àṣà

◼ Nígbà tá a bá ń kọ lẹ́tà

◼ Nígbà tá a bá wà nínú ọkọ̀ èrò

◼ Nígbà tí ẹnì kan bá wá sí ilé wá

◼ Nígbà tá a bá ń bá àwọn ẹbí, àwọn aládùúgbò, àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa, àwọn ọmọ iléèwé wa, àtàwọn ẹlòmíràn tá a mọ̀ sọ̀rọ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́