Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àtúnyẹ̀wò tá a máa ṣe láìṣíwèéwò lórí àwọn ẹ̀kọ́ tá a ti kọ́ nínú àwọn iṣẹ́ àyànfúnni Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run láwọn ọ̀sẹ̀ May 6 sí August 22, 2002. Lo abala bébà ọ̀tọ̀ láti fi kọ ìdáhùn sí púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè náà sílẹ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe fún ọ tó, ní ìwọ̀n àkókò tí a yàn.
[Àkíyèsí: Lákòókò àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, Bíbélì nìkan ni a lè lò láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Àwọn ìtọ́kasí tí ó tẹ̀ lé àwọn ìbéèrè wà fún ìwádìí tìrẹ fúnra rẹ. Nọ́ńbà ojú ìwé àti ìpínrọ̀ lè má fara hàn ní gbogbo àwọn ibi tá a ti tọ́ka sí Ilé Ìṣọ́.]
Dáhùn Bẹ́ẹ̀ ni tàbí Bẹ́ẹ̀ kọ́ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:
1. Jeremáyà 18:1-6 fi hàn pé Jèhófà máa ń mú káwọn èèyàn ṣe ohun tí wọn kò fẹ́ ṣe. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w99-YR 4/1 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 3 àti 4.]
2. Àwọn wòlíì èké jí ipá tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń sà àti ìyọrísí tó ń ní lórí ẹni gbé, nípa fífún àwọn èèyàn níṣìírí láti tẹ́tí sí irọ́ dípò kí wọ́n tẹ́tí sí ìkìlọ̀ tòótọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Jer. 23:30) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w92-YR 2/1 ojú ìwé 4 ìpínrọ̀ 3.]
3. Ní Jeremáyà 25:15, 16, “ife wáìnì ìhónú yìí” tó ń mú “gbogbo orílẹ̀-èdè . . . ṣe bí ayírí” tọ́ka sí bí ìsìn èké ṣe ń mú àwọn ènìyàn hùwà bí arìndìn. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w94-YR 3/1 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 13.]
4. Níbàámu pẹ̀lú ọ̀nà tí Mátíù gbà lo àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà, “ilẹ̀ ọ̀tá” ń tọ́ka sí ilẹ̀ ikú, láti ibi tí àwọn ọmọ kéékèèké tí Hẹ́rọ́dù Ńlá pa yóò ti padà wá nípasẹ̀ àjíǹde. (Jer. 31:15, 16; Mát. 2:17, 18) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w79-YR 12/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 13.]
5. Jeremáyà 37:21 mú un dá wa lójú pé Jèhófà lè pèsè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ láwọn àkókò tí ipò ìṣúnná owó kò bá rọgbọ títí dé òpin ètò àwọn nǹkan yìí, kódà nígbà tí ipò nǹkan bá nira gan an tó sì dà bí ẹni pé kò sí ọ̀nà àbáyọ kankan. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w97-YR 9/15 ojú ìwé 3 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 4 ìpínrọ̀ 2.]
6. Ìwé Ìdárò jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ló ń fúnni ní ìrètí tòótọ́ lákòókò ìbànújẹ́. [w88-YR 9/1 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 5]
7. Ìdárò 5:7 fi hàn kedere pé Jèhófà máa ń fìyà jẹ àwọn ọmọ ní tààràtà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn òbí wọn dá. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 9/1 ojú ìwé 27 àpótí.]
8. Àmì iwájú orí tá a tọ́ka sí nínú Ìsíkíẹ́lì 9:4 túmọ̀ sí pé ìmọ̀ nìkan yóò gba ẹnì kan là. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 9/15 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 18.]
9. “Àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” tí Éfésù 4:8 mẹ́nu kàn ni àwọn Kristẹni alàgbà, tí a fi ẹ̀mí mímọ́ yàn, tí a sì fún ní ọlá àṣẹ láti máa bójú tó ire tẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. (Ìṣe 20:28) [w00-YR 8/1 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 3]
10. Nínú ìmúṣẹ òde òní ti Ìsíkíẹ́lì orí 23, a lè fi ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì wé Òhólíbà a sì lè fi ẹ̀sìn Kátólíìkì wé ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Òhólà. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 9/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 22.]
Dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí:
11. Ta ló ń sìn gẹ́gẹ́ bí “olùṣọ́” tí Jèhófà yàn lónìí, ìdí wo ló sì fi yẹ ká fetí sílẹ̀ nígbà tí “olùṣọ́” náà bá ń sọ̀rọ̀? [w88-YR 9/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 1 àti ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 8]
12. Báwo ni a ṣe lè fi hàn pé a ní ìmọrírì àtọkànwá fún ẹbọ ìràpadà Kristi, ní ti bá a ṣe ń ṣègbọràn sí ìkésíni tó wà nínú Lúùkù 9:23? [w00-YR 3/15 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 1]
13. Lọ́nà wo ni Jèhófà gbà ‘tan’ Jeremáyà? (Jer. 20:7) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w89-YR 5/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 6.]
14. Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ẹ̀mí mímọ́ “yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, tí yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ fún yín padà wá sí ìrántí yín”? (Jòhánù 14:26) [w00-YR 4/1 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 7 àti 8]
15. Níbàámu pẹ̀lú Jeremáyà 35:18, 19, ìrètí wo ni a nawọ́ rẹ̀ jáde fún àwọn ẹgbẹ́ Rékábù ti òde òní? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo su-YR ojú ìwé 131 ìpínrọ̀ 7.]
16. Ọ̀nà wo ni àwọn Néfílímù gbà jẹ́ “alágbára ńlá” àti “àwọn ọkùnrin olókìkí”? (Jẹ́n. 6:4) [w00-YR 4/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 1]
17. Lọ́nà wo ni Bárúkù gbà sọ ìwàdéédéé rẹ̀ nípa tẹ̀mí nù, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i? (Jer. 45:1-5) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w97-YR 8/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 14 sí 16.]
18. Ìgbà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Jeremáyà 50:38 nímùúṣẹ, báwo ló sì ṣe ṣẹlẹ̀? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo dp-YR ojú ìwé 150 ìpínrọ̀ 2 àti 3.]
19. Gẹ́gẹ́ bí Ìdárò 1:15 ṣe sọ, àmì kí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù tí í ṣe “wúńdíá ọmọbìnrin Júdà” jẹ́ fún àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 9/1 ojú ìwé 27 àpótí.]
20. Kí ni ìjẹ́pàtàkì gbólóhùn náà, “Mú láwàní kúrò, sì ṣí adé kúrò,” gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní Ìsíkíẹ́lì 21:26? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 9/15 ojú ìwé 19 sí 20 ìpínrọ̀ 16.]
Pèsè ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn tó yẹ kó wà ní àlàfo inú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:
21. Ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà yóò máa __________________________, ó sì mọ̀ pé ohun tó yẹ kí òun ṣe àti ohun tí òun lè ṣe ní __________________________. (Míkà 6:8) [w00-YR 3/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 1 àti 2]
22. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀mí mímọ́ lè máà mú àwọn __________________________ àti __________________________ kúrò, ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti __________________________ wọ́n. (1 Kọ́r. 10:13; 2 Kọ́r. 4:7) [w00-YR 4/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 6]
23. Láti ọdún __________________________ tí wọ́n ti gba okun nípa tẹ̀mí, __________________________ ti ń fi àìṣojo sọ àwọn ìdájọ́ Ọlọ́run, ìyẹn àwọn ìhìn alágbára tó jẹ́ ti àjálù, èyí tó ń bọ̀ lórí __________________________. (Fi wé Jeremáyà 11:9-13.) [w88-YR 4/1 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 7]
24. __________________________, tó jẹ́ wòlíì àti ẹlẹ́rìí fún Jèhófà ló parí ìwé Ìdárò lọ́dún __________________________. [w88-YR 9/1 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 1]
25. Àpẹẹrẹ Ábúráhámù ní ti jíjuwọ́sílẹ̀ nígbà tá a bá ní aáwọ̀ jẹ́ ìṣírí fún wa láti má ṣe jẹ́ kí __________________________ tàbí __________________________ ba àjọṣe dídára tó wà láàárín àwa àtàwọn arákùnrin wa jẹ́. (Jẹ́n. 13:5-12) [w00-YR 8/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 3 àti 4]
Mú ìdáhùn tó tọ̀nà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:
26. Jóòbù mọyì (ìmọ̀; àánú; ìdájọ́) Jèhófà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lò (tòyetòye; tàánútàánú; lọ́nà yíyẹ). (Jóòbù 31:13, 14) [w00-YR 3/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 1]
27. Ní Jeremáyà 16:2-4, Ọlọ́run pàṣẹ fún wòlíì náà láti wà ní àpọ́n (láti fi ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ rẹ̀ hàn; láti ṣàpẹẹrẹ ìgbésí ayé àpọ́n tí Mèsáyà gbé; láti fìdí ọ̀rọ̀ Jèhófà múlẹ̀ pé dájúdájú, ìparun yóò dé bá Jerúsálẹ́mù). [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w78-YR 10/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 2.]
28. Ní Òwe 4:7, ọgbọ́n ń tọ́ka sí (mímọ̀ nípa àwọn kókó kan; rírí i bí àwọn kókó ṣe so mọ́ra; lílo ìmọ̀ àti òye). [w00-YR 5/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 1]
29. Gbólóhùn náà (“ọmọ jòjòló,” “ẹ ní ìyánhànhàn”) fi hàn pé ọ̀pọ̀ kì í fúnra wọn yán hànhàn fún oúnjẹ tẹ̀mí. (1 Pét. 2:2) [fy-YR ojú ìwé 58 ìpínrọ̀ 17]
30. Kẹ̀kẹ́ ẹṣin Ọlọ́run tí a ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Ìsíkíẹ́lì orí 1 dúró fún (Ìjọba Ọlọ́run ti Mèsáyà náà; ètò àjọ Jèhófà tẹ̀mí tó ní àwọn áńgẹ́lì nínú; ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà bá àwọn àṣẹ́kù sọ̀rọ̀). [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 9/15 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 5.]
So àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tẹ̀ lé e yìí mọ́ èyí tó bá a mu lára àwọn gbólóhùn tí a tò sísàlẹ̀ yìí:
Jer. 18:18; Diu. 11:18, 19; Òwe 5:21; Jer. 46:28; Róòmù 15:4
31. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwùjọ àlùfáà àtàwọn olóṣèlú ń sapá láti dá iṣẹ́ wíwàásù ìdájọ́ Ọlọ́run dúró, àwọn ẹlẹ́rìí rẹ̀ olóòótọ́ ń bá a nìṣó, pẹ̀lú ìpinnu láti parí iṣẹ́ ìkìlọ̀ náà pátápátá. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 4/1 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 19.]
32. Ọ̀nà pàtàkì tí Jèhófà ń gbà pèsè ìtùnú ni nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tá a kọ sílẹ̀, èyí tó ní ìrètí àgbàyanu nípa ọjọ́ ọ̀la nínú. [w00-YR 4/15 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 4]
33. Ìbáwí àwọn òbí kò gbọ́dọ̀ kọjá ààlà bẹ́ẹ̀ ni kò gbọ́dọ̀ ré kọjá ète tó wà fún, ìyẹn ni láti tọ́ni sọ́nà àti láti kọ́ni. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo kl-YR ojú ìwé 148 ìpínrọ̀ 20.]
34. Olórí ìdílé kan tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ ní láti máa lo gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ láti gbé ìdílé rẹ̀ ró kí wọ́n lè jẹ́ ẹni tẹ̀mí. [fy-YR ojú ìwé 70 ìpínrọ̀ 14]
35. Bó ti wù kí ìwà pálapàla takọtabo èyíkéyìí tí ẹnì kan hù pa mọ́ lójú èèyàn tó, kò pa mọ́ lójú Ọlọ́run. [w00-YR 7/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 3]