Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù August àti September: A lè fi èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tó tẹ̀ lé e yìí lọni: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Gbádùn Iwalaaye Lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú?, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” A tún lè fi àwọn ìwé pẹlẹbẹ wọ̀nyí, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn àti Ìwọ́ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, lọni níbi tó bá ti bá àkókò mu. October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Níbi tí ẹnì kan bá ti fi ìfẹ́ hàn, fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọ̀ ọ́, kí o sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. November: Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tàbí Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Bí onílé bá ti ní àwọn ìwé wọ̀nyí, o lè fi ìwé kan tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ lọ̀ ọ́.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí ó bá yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní September 1 tàbí bí ó bá ti lè yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ti ṣe èyí, ẹ ṣèfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó ti oṣù tó ń bọ̀.
◼ Ní August 31, 2002 tàbí bí ó bá ti lè yá tó lẹ́yìn náà, kí ẹ ṣírò gbogbo iye ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́ bí a ti ń ṣe lọ́dọọdún. Ìṣirò yìí jọ èyí tí ẹni tó ń ṣe kòkáárí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ máa ń ṣe lóṣooṣù nípa kíka iye àwọn ìwé náà lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan. Kí ẹ kọ àròpọ̀ iye wọn sórí fọ́ọ̀mù Literature Inventory (S-18). Ẹ lè mọ àròpọ̀ iye ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìwé ìròyìn ní ìjọ kọ̀ọ̀kan tí ẹ jọ ń gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ pọ̀. Gbogbo ìjọ tí ń ṣe kòkáárí yóò gba fọ́ọ̀mù Literature Inventory (S-18) mẹ́ta-mẹ́ta. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi ẹ̀dà àkọ́kọ́ ránṣẹ́ sí Society, ó pẹ́ tán ní September 6. Ẹ tọ́jú ẹ̀dà kejì sínú fáìlì yín. Ẹ lè lo ẹ̀dà kẹta gẹ́gẹ́ bí èyí tí ẹ óò kọ́kọ́ lò fún ìṣirò. Kí akọ̀wé ìjọ tí ń ṣe kòkáárí bójú tó ìṣirò ọlọ́dọọdún náà. Akọ̀wé àti alábòójútó olùṣalága ìjọ tí ń ṣe kòkáárí ni kó fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù náà.
◼ Láti August 26 sí August 31, 2002, Society yóò ka gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà lọ́wọ́ ní Bẹ́tẹ́lì Igieduma. Nítorí ìṣirò tí a fẹ́ ṣe yìí, a kò ní ṣiṣẹ́ lórí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ìjọ béèrè pé kí a fi ránṣẹ́ ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí.
◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà: Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì —Onílẹ́tà Gàdàgbà—Gẹ̀ẹ́sì
Ìdìpọ̀ Jí! ọdún 2001—Gẹ̀ẹ́sì