Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 12
Orin 76
13 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ August 15 àti Jí! September 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, fi hàn bí a ṣe lè fèsì àwọn ọ̀rọ̀ tó lè bẹ́gi dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, irú bí “Èé Ṣe Tí Ẹ Fi Ń Wá Síbí Lemọ́lemọ́?”—Wo ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 12.
20 min: “Gbé Àwọn Ohun Tẹ̀mí Tí Wàá Máa Lépa Kalẹ̀.”a Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 5, fi àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fúnni níṣìírí láti ṣe iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà déédéé, sísìn níbi tí àìní ti pọ̀ àti iṣẹ́ ìsìn ní Bẹ́tẹ́lì kún un látinú ìwé Ìṣètòjọ, ojú ìwé 112 sí 116.
12 min: “Àwọn Èèyàn Tó Jẹ́ Aláyọ̀ Jù Lọ Lórí Ilẹ̀ Ayé.”bNí ṣókí, fi àlàyé kún un látinú àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ìgbésẹ̀ Sí Jíjẹ́ Aláyọ̀,” nínú Ilé Ìṣọ́ October 15, 1997, ojú ìwé 6.
Orin 57 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 19
Orin 182
8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: Kí Ló Mú Kí Wọ́n Máa Lọ́ Tìkọ̀? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ àti àṣefihàn. Nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a sábà máa ń pàdé àwọn èèyàn tí wọn kì í fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Èyí máa ń ṣèdíwọ́ fún wa láti sọ ìhìn Ìjọba náà. Tá a bá mọ ohun tó fà á tí ẹnì kan fi ń lọ́ tìkọ̀, èyí lè ràn wá lọ́wọ́ láti múra ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan sílẹ̀, tó máa fún ẹni náà níṣìírí láti sọ èrò ọkàn rẹ̀ jáde. Jíròrò bí a ṣe lè yí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ wa padà nígbà tá a bá pàdé irú àwọn èèyàn tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí: (1) Àwọn tí kò ka ọ̀ràn ìsìn sí, kódà ìsìn tiwọn fúnra wọn pàápàá. (2) Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ gidi nínú ìsìn tí ìdílé wọn àtàwọn baba ńlá wọn ń ṣe. (3) Àwọn tí wọn kì í fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ wọn nítorí pé wọn ò lè fi Ìwé Mímọ́ gbe ọ̀rọ̀ wọn lẹ́sẹ̀. (4) Àwọn tó ní ẹ̀tanú sí wa nítorí àwọn ọ̀rọ̀ aṣinilọ́nà tí wọ́n ti gbọ́ lẹ́nu àwọn alátakò. Ó lè ṣàtúnṣe sí àwọn ohun tó wà lókè yìí tó bá pọn dandan kó lè bá ìpínlẹ̀ yín mu, nípa dídarí àfiyèsí sí àwọn ìṣarasíhùwà tí ẹ sábà máa ń bá pàdé. Ṣe àṣefihàn kúkúrú kan tó máa fi hàn bí a ṣe lè fún ẹnì kan níṣìírí láti jíròrò Ìwé Mímọ́.
22 min: “A Ti Ní Irinṣẹ́ Tuntun fún Bíbẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́!” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ, èyí tí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn yóò bójú tó. Bí ìwé àṣàrò kúkúrú tuntun náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì? bá wà, ní kí àwọn tó ń tọ́jú èrò pín in fún gbogbo àwọn tó wá sí ìpàdé. Fún àwọn ará ní ìṣírí láti fún gbogbo ẹni tí wọ́n bá bá pàdé nínú iṣẹ́ ìwàásù ní ìwé àṣàrò kúkúrú tuntun náà.
Orin 191 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 26
Orin 189
12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Nípa lílo àbá tó wà ní ojú ìwé 8, jẹ́ kí aṣáájú ọ̀nà déédéé kan tàbí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ kan ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ September 1 lọni. Rọ gbogbo àwọn akéde láti lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan nígbà tí wọ́n bá ń gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀.
18 min: “Jẹ́ Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ Tí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Ń Wọni Lọ́kàn!”c
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ. Tàbí kó o ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ti ní nígbà tí wọ́n ń wàásù láwọn ọ̀nà mìíràn yàtọ̀ sí ìjẹ́rìí ilé-dé-ilé. Bóyá nígbà tí wọ́n ń wàásù ìhìnrere náà fún àwọn èèyàn láwọn ibùdókọ̀, nínú ọkọ̀ èrò, láwọn ibi ìgbafẹ́, láwọn ibi ìtajà, níbi táwọn ọkọ̀ ẹlẹ́rù máa ń páàkì sí, àti láwọn ibòmíràn tí èrò máa ń pọ̀ sí. Ṣe àṣefihàn bí ọ̀kan tàbí méjì nínú àwọn ìrírí náà ṣe ṣẹlẹ̀.
Orin 99 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 2
Orin 84
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù August sílẹ̀. Ní ṣókí, sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà, “Máa Kàwé Pẹ̀lú Àwọn Ọmọ Rẹ” èyí tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ May 1, 1999, ojú ìwé 25.
20 min: Múra Sílẹ̀ Kó O Tó Ó Lọ. Ìjíròrò àti àṣefihàn. Ìwéwèé tá a ṣe dáadáa máa ń mú ká túbọ̀ jáfáfá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Nítorí náà, ṣáájú ìgbà tó o máa lọ òde ẹ̀rí: (1) Gba àwọn ìwé tí wàá nílò. (2) Rí i dájú pé o ní ìwé àkọsílẹ̀ ilé-dé-ilé (house-to-house record) tó máa tó ó lò àti ohun ìkọ̀wé lọ́wọ́. (3) Bó o bá máa nílò láti wọkọ̀ dé ibi tó ò ń lọ, ṣe ètò tó yẹ sílẹ̀. (4) Ronú nípa àwọn ìpadàbẹ̀wò tó o wéwèé láti ṣe. (5) Múra ohun tó o máa sọ sílẹ̀. Bó bá jẹ́ ìwọ ni wàá darí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, gba ìpínlẹ̀ tó tó ṣáájú. Jíròrò pẹ̀lú àwùjọ, ọ̀nà méjì tàbí mẹ́ta tí a lè gbà fi èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ìwé 32 lọni nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú oṣù September. Ṣàṣefihàn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan, kó o sì lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan nínú ìjíròrò náà.—Wo àwọn ìdámọ̀ràn nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti August 1996, ojú ìwé 8, àti ti July 1995, ojú ìwé 8.
15 min: Àwọn ìrírí tí àwọn akéde ní. Ké sí àwọn ará láti sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń lo ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì? Ǹjẹ́ wọ́n ti lò ó láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì èyíkéyìí? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ní kí wọ́n ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ṣe é tàbí kí wọ́n ṣàṣefihàn ọ̀kan tàbí méjì nínú àwọn ìrírí náà. Gbé àpótí náà, “Àwọn Ọ̀nà Tá a Lè Gbà Fún Àwọn Èèyàn Ní Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Náà” tó wà ní ojú ìwé 4 yẹ̀ wò.
Orin 123 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.