Àwọn Èèyàn Tó Jẹ́ Aláyọ̀ Jù Lọ Lórí Ilẹ̀ Ayé
1 “Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!” (Sm. 144:15) Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà hàn gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn tó láyọ̀ jù lọ lórí ilẹ̀ ayé. Kò sí ayọ̀ kankan tó ju ayọ̀ tó ń wá látinú sísin Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ àti Ọlọ́run alààyè kan ṣoṣo náà. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀,” àwọn tó ń sìn ín ń gbé ìdùnnú rẹ̀ yọ. (1 Tím. 1:11) Kí ni díẹ̀ lára àwọn apá ìjọsìn wa tó ń mú ká jẹ́ aláyọ̀ gan-an?
2 Àwọn Ohun Tó Ń Mú Ká Jẹ́ Aláyọ̀: Jésù mu dá wa lójú pé, ayọ̀ máa ń wá látinú jíjẹ́ kí ‘àìní wa nípa ti ẹ̀mí máa jẹ wá lọ́kàn.’ (Mát. 5:3) Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà gbogbo àti wíwá sí gbogbo àwọn ìpàdé Kristẹni la fi ń bójú tó àìní yẹn. Mímọ òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti sọ wá dòmìnira kúrò nínú ìsìn èké àtàwọn ìṣìnà tó kúnnú rẹ̀. (Jòh. 8:32) Ìwé Mímọ́ tún ti kọ́ wa ní ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà gbé ìgbésí ayé. (Aísá. 48:17) Fún ìdí yìí, à ń gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Kristẹni tó gbámúṣé láàárín àwọn ẹgbẹ́ ará wa tó jẹ́ aláyọ̀.—1 Tẹs. 2:19, 20; 1 Pét. 2:17.
3 À ń rí ìtẹ́lọ́rùn tó ga nínú ṣíṣègbọràn sí àwọn ìlànà ìwà rere gíga ti Ọlọ́run, níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé èyí ń dáàbò bò wá ó sì ń mú Jèhófà láyọ̀. (Òwe 27:11) Akọ̀ròyìn kan sọ pé: “Laika awọn ọpa idiwọn wọn ti ko gba gbẹ̀rẹ́ si, awọn Ẹlẹrii Jehofah ko farahan [bi] alailayọ. Odikeji ni. Awọn ọ̀dọ́ ati agba [to wa laaarin wọn] a maa fi irisi lilayọ ati wiwa ni iwọntun-wọnsi li ọna ara-ọ̀tọ̀ hàn.” Báwo la ṣe lè ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ káwọn náà bàa lè gbé irú ìgbésí aláyọ̀ tí à ń gbé?
4 Ran Àwọn Mìíràn Lọ́wọ́ Láti Rí Ayọ̀: Ìbànújẹ́ ló kúnnú ayé fọ́fọ́, ńṣe ni ọjọ́ iwájú sì pòkúdu fún àwọn èèyàn ní gbogbo gbòò. Àmọ́ ṣá o, pẹ̀lú ayọ̀ la fi ń wo ọjọ́ iwájú, nítorí a mọ̀ pé lọ́jọ́ kan, gbogbo ohun tó ń fa ìbànújẹ́ pátá ló máa di ohun ìgbàgbé. (Ìṣí. 21:3, 4) Nípa bẹ́ẹ̀, tìtaratìtara la fi ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, tí à ń wá àwọn olóòótọ́ ọkàn láti bàa lè sọ fún wọn nípa ìrètí wa àtàwọn ohun tá a gbà gbọ́ nípa Jèhófà.—Ìsík. 9:4.
5 Arábìnrin kan tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà sọ pé: “Kò sí ohun kan tí ń mú ìtẹ́lọ́rùn wá ju ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà àti òtítọ́ rẹ̀.” Ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran ọ̀pọ̀ èèyàn sí i lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. Ṣíṣiṣẹ́sin Jèhófà àti lílo ara wa nínú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti sìn ín ń mú ayọ̀ tó ga lọ́lá wá.—Ìṣe 20:35.