Máa Múra Tán Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
1. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ pa àṣẹ tí Jésù pa fún wa ní Mátíù 28:19, 20 mọ́?
1 Jésù pàṣẹ fún wa láti máa “sọ àwọn ènìyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn,” ká sì “máa kọ́ wọn.” (Mát. 28:19, 20) Ìdí nìyẹn tá a fi gbọ́dọ̀ máa wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn, ká má fi mọ sí ọjọ́ tí ìjọ wa yà sọ́tọ̀ lópin ọ̀sẹ̀ kan lóṣooṣù. Àwọn àbá tó tẹ̀ lé e yìí lè ràn wá lọ́wọ́.
2. Àwọn wo la lè fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ?
2 Máa Fi Lọ Àwọn Èèyàn: Bá a bá ṣe túbọ̀ ń fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn èèyàn, ìyẹn á jẹ́ ká láǹfààní láti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì púpọ̀ sí i. (Oníw. 11:6) Ṣé o ti gbìyànjú láti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn èèyàn ní tààràtà? Ìjọ kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà gbìyànjú èyí fún odindi oṣù kan. Inú wọn dùn gan-an pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú èèyàn méjìlélógójì [42]! Má kàn rò pé àwọn tó o wàásù fún ti mọ̀ pé a máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó o bá pa dà bẹ̀ wọ́n wò, o ò ṣe sọ pé o fẹ́ wá máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Bí wọn ò bá gbà pé kó o máa wá kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, má mikàn. O ṣì lè máa ṣe ohun táá mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ǹjẹ́ o ti béèrè lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò rẹ, àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ, àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn ọmọléèwé rẹ bóyá wọ́n á fẹ́ kó o máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? O tún lè béèrè lọ́wọ́ àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bóyá wọ́n ní àwọn ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí tó ṣeé ṣe kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
3. Ìwé wo ló wúlò fún bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn ìgbà wo la sì lè lò ó?
3 Ìwé Tó Gbéṣẹ́: Ìwé kan tó wúlò láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? A lè fún onílé ní ìwé àṣàrò kúkúrú yìí, yálà ó gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ míì tàbí kò gbà á. A tún lè lo ìwé àṣàrò kúkúrú yìí láwọn ìpínlẹ̀ táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé, tá a bá ń jẹ́rìí ní òpópónà, tá a bá ń fi lẹ́tà ránṣẹ́ àti nígbà tá a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò. A tiẹ̀ tún lè fi sí ẹnu ọ̀nà àwọn tá ò bá nílé. O ò ṣe máa mú ìwé àṣàrò kúkúrú yìí dání nígbà tó o bá ń wọ ọkọ̀ èrò, tó o bá ń lọ sí ọjà àti nígbà tó o bá ń lọ síbi iṣẹ́? Àlàyé ṣókí lórí bá a ṣe ń lo ìwé Bíbélì fi Kọ́ni láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wà lójú ewé tó gbẹ̀yìn ìwé àṣàrò kúkúrú náà.
4. Báwo la ṣe lè lo ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
4 Lẹ́yìn tó o bá ti mú ìwé àṣàrò kúkúrú náà fún ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀, o lè fi àwọn ìbéèrè tó wà lójú ìwé àkọ́kọ́ yẹn hàn án, kó o wá bi í pé, “Èwo nínú àwọn ìbéèrè yìí lo nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ?” Lẹ́yìn náà, kẹ́ ẹ wá jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tí ẹni náà bá yàn nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà, kó o sì ka àlàyé tó wà lójú ìwé tó gbẹ̀yìn nínú ìwé náà lórí bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí kó o ṣàkópọ̀ rẹ̀ ní ṣókí. O lè fún un ní ìwé Bíbélì fi Kọ́ni, kó o sì fi àlàyé síwájú sí i lórí ìbéèrè tẹ́ ẹ dáhùn náà hàn án nínú rẹ̀. Ṣètò láti pa dà bẹ̀ ẹ́ wò kẹ́ ẹ lè jọ máa bá ìjíròrò náà lọ.
5. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa múra tán láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
5 Àwọn èèyàn tó ń fẹ́ mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an ṣì wà láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Tá a bá ń múra tán láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a óò túbọ̀ láǹfààní láti ní ayọ̀ tó ń wá látinú ríran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá sí ọ̀nà tó lọ sí ìyè.—Mát. 7:13, 14.