ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/15 ojú ìwé 1
  • Máa Pọkàn Pọ̀ Sórí Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Pọkàn Pọ̀ Sórí Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Múra Tán Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Ṣé Ìwọ Náà Lè Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Máa Fi Òtítọ́ Kọ́ni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Ìmúrasílẹ̀—Ọ̀nà Kan Ṣoṣo Láti Ṣe Ìpadàbẹ̀wò Tó Múná Dóko
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
km 7/15 ojú ìwé 1

Máa Pọkàn Pọ̀ Sórí Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn

1. Kí la lè ṣe kí àwọn èèyàn lè rí ìgbàlà?

1 Ìròyìn iṣẹ́ ìsìn wa ti ọdún 2014 fi hàn pé àwa èèyàn Ọlọ́run ní ìtara, a sì ti pinnu láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 24:14) A túbọ̀ ń rí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ju ti tẹ́lẹ̀ lọ bá sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run nípasẹ̀ ìwàásù láti ilé dé ilé, ìpolongo àkànṣe tá a máa ń ṣe nígbà tá a bá ń pín ìwé àṣàrò kúkúrú àtàwọn ìwé ìkésíni àti àkànṣe ìwàásù láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí. Àmọ́, kí àwọn èèyàn tó lè rí ìgbàlà, a ní láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa kíkọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn Kristi.—1 Tím. 2:4.

2. Àwọn ìbéèrè wo la lè bi ara wa táá fi hàn pé ó ń wù wá láti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

2 Jẹ́ Kó Máa Wù Ọ́ Láti Ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: Tó o bá bá ẹnì kan sọ̀rọ̀, tó sì nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ, ṣé o máa ń gba àdírẹ́sì rẹ̀ kó o sì sapá láti padà lọ bẹ̀ ẹ́ wò, kó o lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ṣé o ti gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tó o bá ẹnì kan sọ̀rọ̀? Ṣé o ti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn tó o máa ń fún ní ìwé ìròyìn déédéé? Ǹjẹ́ o ti fi fídíò náà, Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? àti Báwo La Ṣe Máa Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? han àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọléèwé rẹ, àwọn aládùúgbò rẹ, àwọn ìbátan rẹ àtàwọn ẹlòmíì? Tó o bá pàtẹ ìwé wa síbì kan, ṣé o máa ń sọ fún àwọn tó bá mú ìwé tá a fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pé a máa ń bá àwọn èèyàn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́?

3. Kí ló yẹ ka ṣe ká lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́?

3 Jèhófà àti Jésù Ń Ràn Wá Lọ́wọ́: Bí Jésù ṣe sọ pé “ẹ lọ” nígbà tó pàṣẹ pé ká máa ‘sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn’ jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká máa sapá ká sì máa wàásù ní onírúurú ọ̀nà. Àmọ́, Jésù kò dá iṣẹ́ yìí dá wa, ó sọ pé òun á wà pẹ̀lú wa. (Mát. 28:19, 20) Bákan náà, Jèhófà ń fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àtàwọn ohun tá a nílò láti ṣe iṣẹ́ yìí, ó sì tún ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ ká lè máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. (Sek. 4:6; 2 Kọ́r. 4:7) A lè gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kó máa wù wá “láti ṣe” iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, kí á sì “gbé ìgbésẹ̀” láti ṣe iṣẹ́ pàtàkì yìí.—Fílí. 2:13.

4. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa pọkàn pọ̀ sórí sísọni di ọmọ ẹ̀yìn?

4 Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ayọ̀ wa á túbọ̀ kún tá a bá kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, tí òun náà sì wá ń rìn ní ‘ojú ọ̀nà tó lọ sí ìyè.’ (Mát. 7:14; 1 Tẹs. 2:19, 20) Ní pàtàkì jù lọ, tá a bá ń pọkàn pọ̀ sórí sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, a ó mú inú Jèhófà dùn, ẹni tí ‘kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n tó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.’—2 Pét. 3:9.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́