Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ July 13
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 13
Orin 75 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 27 ìpínrọ̀ 10 sí 18 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 9-11 (8 min.)
No. 1: 1 Àwọn Ọba 9:24–10:3 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: A Lè Dín Àníyàn Kù Tá A Bá Fi Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Sọ Sílò—igw ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 2 (5 min.)
No. 3: Ẹ̀kọ́ Táwọn Ọ̀dọ́ Lè Kọ́ Lára Hesekáyà àti Jòsáyà Ọba (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: ‘Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn.’ —Mát. 28:19, 20.
10 min: Ẹ Lọ, Kí Ẹ sì Máa Sọ Àwọn Ènìyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn. Àsọyé tó dá lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ oṣù yìí. Fi àwọn kókó tó wà nínú ìwé “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn,” ojú ìwé 87 sí 89 kún ọ̀rọ̀ rẹ. Sọ díẹ̀ lára àwọn apá Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn oṣù yìí, kó o sì jíròrò bó ṣe tan mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ oṣù yìí.
10 min: Wọ́n Gbára Dì Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìjíròrò tá a gbé ka Ìwé Ọdọọdún 2015, ojú ìwé 55, ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 56, ìpínrọ̀ 1 àtiojú ìwé 69, ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 70, ìpínrọ̀ 1. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
10 min: “Máa Pọkàn Pọ̀ Sórí Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tí wọ́n mọ bá a ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti bá a ṣe ń darí rẹ̀ lọ́nà tó múná dóko. Ayọ̀ wo ni wọ́n ti rí nínú bí wọ́n ṣe ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́?
Orin 16 àti Àdúrà