Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Ilé Ìṣọ́ July 1
“Pẹ̀lú bí ìdààmú ṣe pọ̀ láyé yìí, ṣé o rò pé ó bọ́gbọ́n mu bí Jésù ṣe sọ pé ká má ṣe máa ṣàníyàn? [Ka Mátíù 6:25, kó o sì jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí sọ nípa bí àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti dín àníyàn nípa owó, ìṣòro ìdílé àti ọ̀rọ̀ ààbò kù.”
Ji! July–August
“Torí pé àìsàn ń bá ọ̀pọ̀ èèyàn fínra, a wá ṣèbẹ̀wò ráńpẹ́ sọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò wa ká lè sọ̀rọ̀ nípa ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí. [Ka Aísáyà 33:24a.] Báwo lo ṣe rò pé ìgbésí ayé wa ṣe máa rí tá ò bá ṣàìsàn mọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Kó tó dìgbà tí asọtẹ́lẹ̀ yìí á nímùúṣẹ, àwọn nǹkan márùn-ún kan wà tá a lè ṣe láti mú kí ìlera wa sunwọ̀n sí i. Ìwé ìròyìn yìí sọ àwọn nǹkan náà.”