Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ June 1
“Ǹjẹ́ o rò pé gbogbo ẹ̀sìn ni inú Ọlọ́run dùn sí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ó dùn mọ́ni nínú láti rí ọwọ́ tí Ọlọ́run fi mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì nígbà tí wọ́n lọ ń jọ́sìn ọlọ́run àwọn orílẹ̀ èdè tó yí wọn ká. [Ka Ìsíkíẹ́lì 6:6.] Àpilẹ̀kọ yìí dáhùn ìbéèrè náà, ‘Ṣé Bó Ṣe Wù Wá La Ṣe Lè Sin Ọlọ́run?’” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 9 hàn án.
Ile Iṣọ July 1
“Gbogbo wa la ti ní ìrírí ìbànújẹ́ tó máa ń bá èèyàn nígbà téèyàn ẹni bá ṣaláìsí. Nírú àwọn àkókò báyìí, ǹjẹ́ o rò pé Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Sáàmù 55:22.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé àwọn àbá tó gbéṣẹ́, tó wà nínú Bíbélì, tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á béèyàn wa bá ṣaláìsí.”
Jí! Apr.–June
“Nítorí ọ̀pọ̀ nǹkan tá a máa ń fàkókò wa ṣe, ó máa ń ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti ya àkókò sọ́tọ̀ fún ìjọsìn Ọlọ́run. Ìwọ ńkọ́? Ṣé bó ṣe máa ń ṣe ìwọ náà nìyẹn? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Éfésù 5:15-17.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé tó bọ́gbọ́n mu látinú Bíbélì nípa iye àkókò àti okun wa tí Ọlọ́run ń fẹ́ ká yà sọ́tọ̀ fún òun.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 14 hàn án.
“Kò síbi táwọn èèyàn ò ti ń ṣépè. Ojú wo lo rò pé Ọlọ́run fi ń wo irú àṣà bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka àṣẹ tí Ẹlẹ́dàá pa nínú Éfésù 4:31 nípa bó ṣe yẹ ká máa lo ahọ́n wa.] Àpilẹ̀kọ Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé. . . yìí ṣàlàyé ọ̀nà mẹ́ta tá a lè gbà máa yẹra fún fífi ahọ́n wa sọ̀sọkúsọ.”