Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ July 15
“Bí èèyàn ẹni bá kú, ìbànújẹ́ ńlá gbáà ló máa ń jẹ́. Ǹjẹ́ lóòótọ́ ni nǹkan kan wà lára wọn tí kì í kú? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìlérí tí ń múni lọ́kàn yọ̀ tí Jésù ṣe rèé. [Ka Jòhánù 5:28, 29.] Níwọ̀n bí Jésù ti sọ pé àjíǹde “ń bọ̀,” ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ibi tí Bíbélì sọ pé àwọn òkú wà báyìí.”
Ile Iṣọ Aug. 1
“Màá fẹ́ mọ èrò ẹ lórí gbólóhùn kan tí Jésù sọ. [Ka Mátíù 5:3.] Ǹjẹ́ o rò pé ó dìgbà téèyàn bá sún mọ́ Ọlọ́run kéèyàn tó lè láyọ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ ohun tó túmọ̀ sí láti sún mọ́ Ọlọ́run àti bá a ṣe lè sún mọ́ ọn.”
Jí! July–Sept.
“Àwọn èèyàn kan ń yí nínú ọlá, ọ̀kẹ́ àìmọye míì sì wà tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́. Ǹjẹ́ o rò pé ìgbà kan á wà tí ò ní sẹ́ni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwọ wo ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́. [Ka Sáàmù 22:24.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa ṣe fáwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́.
“Ṣó o lérò pé Ọlọ́run ti kádàrá ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo ẹ̀dá tó bá wà láyé? [Jẹ́ kó fèsì.] Gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe sọ, Ọlọ́run fáwa èèyàn lómìnira láti yan ohun tá a bá fẹ́ fi ìgbésí ayé wa ṣe. [Ka Diutarónómì 30:19] Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa kádàrá.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 10 hàn án.