Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ July 1
“Ǹjẹ́ o rò pé ó ṣeé ṣe kí àjọṣe tímọ́tímọ́ wà láàárín àwa èèyàn lásán-làsàn àti Ọlọ́run Olódùmarè? [Jẹ́ kó fèsì, kó o wá ka Ìṣe 17:27.] Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò ìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run fẹ́ kí àwa àtòun ní àjọṣe tímọ́tímọ́.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 10 hàn án.
Ile Iṣọ Aug. 1
“Bí àyíká ṣe túbọ̀ ń bà jẹ́ sí i ti mú káwọn kan máa ṣiyè méjì nípa bí ilẹ̀ ayé ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kó fèsì, kó o wá ka Sáàmù 37:11.] Ìwé ìròyìn yìí tẹnu mọ́ àwọn ìdí kan tó bá Ìwé Mímọ́ mu tó mú un dájú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára.”
Jí! July–Sept.
“Ṣe ni ọ̀ọ̀dẹ̀ túbọ̀ ń gbóná mọ́ àwọn lọ́kọláya, ọ̀pọ̀ wọn ló sì ń tipa bẹ́ẹ̀ kọ ara wọn sílẹ̀. Ẹ gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ ní Òwe 12:18. Ṣé ẹ rò pé ìmọ̀ràn tá a kà yìí lè mú káwọn tọkọtaya túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò àwọn ìlànà míì látinú Bíbélì tó lè mú kí àwọn tọkọtaya túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn.”
Ka Mátíù 6:10, kó o wá bi í pé: “Ǹjẹ́ ìbéèrè yìí ti sọ sí ẹ lọ́kàn rí pé, kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá ayé yìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Gẹ́gẹ́ bí àlàyé tó wà nínú Bíbélì, Ọlọ́run ní nǹkan kan lọ́kàn tó fi dá ayé yìí, ohun tó sì ní lọ́kàn yẹn ò tíì yí padà. Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé nǹkan ọ̀hún.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé kẹwàá hàn án.