Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Aug. 1
“Ṣó o gbà pé ìdílé lè túbọ̀ láyọ̀ tí bàbá, ìyá àtàwọn ọmọ bá ṣe ohun tí Jésù pa láṣẹ nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí? [Ka Jòhánù 13:34. Kó o wá jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé báwọn ẹ̀kọ́ Jésù àti àpẹẹrẹ rere rẹ̀ ṣe kan ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 16 àti 17 hàn án.
Ile Iṣọ Sept. 1
“Ṣàṣà lẹni tí ò mọ ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù 6:9. [Kà á.] Síbẹ̀, ó ṣì máa ń ṣòro fún ọ̀pọ̀ láti sún mọ́ Ọlọ́run bíi Bàbá. Kí lo rò pé a lè ṣe láti sún mọ́ Ọlọ́run? [Jé kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò oríṣiríṣi àwọn ànímọ́ Bàbá wa ọ̀run àti bá a ṣe lè mọ̀ ọ́n dáadáa.”
Jí! July–Sept.
“Púpọ̀ lára àwọn fíìmù, orin àtàwọn nǹkan míì táwọn èèyàn fi ń najú lónìí túbọ̀ ń jẹ́ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìbẹ́mìílò. Ṣó o rò pé kò séwu kankan nínú kéèyàn máa lọ́wọ́ sí ìbẹ́mìílò? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Diutarónómì 18:10-12.] Àpilẹ̀kọ yìí sọ àwọn ewu tí Bíbélì sọ pé ó wà nínú ìbẹ́mìílò.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 14 hàn án.
“Ìlànà wo lo rò pó gbéṣẹ́ tó lè mú kí ìgbéyàwó kẹ́sẹ járí? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Òwe 12:18.] Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọ̀ pé ohun tó ṣe pàtàkì jù nínú ìgbéyàwó kì í ṣe ohun téèyàn sọ, àmọ́ bó ṣe sọ ọ́. Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn tọkọtaya máa bára wọn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 6 hàn án.