Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ Aug. 15
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fẹ́ láti ní orúkọ rere. Àwọn kan tiẹ̀ máa ń ṣe kàyéfì nípa ohun táwọn èèyàn máa sọ nípa wọn nígbà tí wọ́n bá kú. Ǹjẹ́ o ti ronú nípa ìyẹn rí? [Jẹ́ kí ó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Oníwàásù 7:1.] Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ yìí ṣàlàyé ọ̀nà tá a lè gbà ṣe orúkọ rere pẹ̀lú èèyàn àti pẹ̀lú Ọlọ́run.”
Ilé Ìṣọ́ Sept. 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ronú pé onírúurú ẹ̀sìn tí aráyé ń ṣe wulẹ̀ jẹ́ ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó lọ sí ibì kan náà. Àwọn mìíràn sì gbà gbọ́ pé ẹ̀sìn tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà. Ǹjẹ́ o ti ṣe kàyéfì nípa èyí rí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé àkàwé ayé àtijọ́ kan tó tànmọ́lẹ̀ sórí ìbéèrè yìí.” Fa kókó ọ̀rọ̀ inú Mátíù 13:24-30 yọ.
Jí! Sept. 8
“Bí wọ́n bá ti fòòró ìwọ tàbí ẹnì kan nínú ìdílé rẹ rí, wàá mọ bó ṣe ń bani nínú jẹ́ tó. [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìtẹ̀jáde Jí! yìí ní àwọn àbá tó lè ṣèrànwọ́ fún àwọn tí à ń fòòró. Ó tún ṣàlàyé nípa ìlérí Ọlọ́run pé àkókò kan ń bọ̀ nígbà tí aráyé kì yóò ní irú ìṣòro yẹn mọ́ rárá.” Ka Míkà 4:4.
“Àṣà aṣọ wíwọ̀ ń ní ipa lílágbára lórí ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí. Àwọn kan rò pé àwọn èèyàn ti ń ṣàníyàn jù nípa aṣọ tí wọ́n á wọ̀ àti ìrísí wọn. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìtẹ̀jáde Jí! yìí sọ bí a ṣe lè wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì tó bá dọ̀ràn aṣọ wíwọ̀.” Ka Kólósè 3:12.