Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Aug. 15
“Lẹ́yìn tẹ́nì kan bá dédé fò ṣánlẹ̀ tó kú, ìbéèrè táwọn èèyàn máa ń béèrè ni pé, ibo ló lọ. Ṣó o rò pé ó ṣeé ṣe láti lóye ohun tá à ń pè ní ikú? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ipò táwọn òkú wà. Ó tún jíròrò bí Ọlọ́run ṣe máa jí àwọn èèyàn wa tó ti kú dìde.” Ka Jòhánù 5:28, 29.
Ile Iṣọ Sept. 1
“Nínú ayé tá à ń gbé yìí, orí ahọ́n nìkan ni òótọ́ inú ti níyì, àwọn èèyàn ò fi ṣèwàhù. Báwo ló ṣe máa rí ná bí èyí tó pọ̀ nínú ọmọ aráyé bá dà bí ọ̀rẹ́ tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ? [Ka Òwe 17:17. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò oore tó wà nínú kéèyàn máa fi òótọ́ inú bá àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ lò.”
Jí Sept. 8
“Ǹjẹ́ o mọ̀ pé wọ́n ní ìrìn-àjò afẹ́ nibi tówó ti ń wọlé jù lágbàáyé? [Jẹ́ kó fèsì.] Báwọn tó ń rìnrìn-àjò afẹ́ ṣe ń pọ̀ sí i yìí ti ṣe ọ̀pọ̀ lóore, ó sì ti kó àwọn míì sí ìṣòro. Ìwé ìròyìn yìí tanná wo ìrìn àjò afẹ́ òde òní, níwá àti lẹ́yìn. Àwọn tó ń rìnrìn-àjò lọ sí orílẹ̀-èdè míì á sì tún rí àwọn àbá tó wúlò nínú ẹ̀.”