ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/04 ojú ìwé 4
  • Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 8/04 ojú ìwé 4

Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn

Ile Ìṣọ́ Aug. 15

“Lóde òní, oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn èèyàn ń gbà wá ìrànlọ́wọ́ lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó àti ọmọ títọ́. Ibo lo rò pé a ti lè rí ìmọ̀ràn tó máa ṣeni láǹfààní jù? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí ṣàlàyé díẹ̀ lára àwọn ìmọ̀ràn tó mọ́gbọ́n dání tí Ẹlẹ́dàá pèsè fún wa lórí ọ̀ràn ìdílé.” Ka Sáàmù 32:8.

Ile Ìṣọ́ Sept. 1

“Gbogbo wa la fẹ́ jẹ́ aláyọ̀. Ǹjẹ́ o rò pé àwọn ohun tá a mẹ́nu kàn nínú ẹsẹ Bíbélì yìí lè fúnni láyọ̀ lóòótọ́? [Ka Mátíù 5:4a, 6a, 10a. Lẹ́yìn náà jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí nígbà tó ń ṣe Ìwàásù Orí Òkè tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ dáadáa yẹn, ó sì tún ṣàlàyé àwọn ohun mìíràn tó lè fúnni láyọ̀.”

Jí! Sept. 8

“Báwo lo ṣe rò pé ó ṣe pàtàkì tó pé kí bàbá máa dá sí ọ̀ràn àwọn ọmọ rẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn Jí! yìí sọ̀rọ̀ lórí ìṣòro bí àwọn bàbá tí kì í wá àyè láti bójú tó àwọn ọmọ wọn ṣe ń pọ̀ sí i. Ó tún ṣàlàyé bí àwọn bàbá ṣe lè ní ipa tó dára lórí àwọn ọmọ wọn.” Ka Òwe 13:1.

“Àwọn olùṣèwádìí fojú díwọ̀n rẹ̀ pé nǹkan bí ìdámẹ́rin àwọn èèyàn àgbáyé ló máa ní àrùn ọpọlọ ní àkókò kan tàbí òmíràn nígbèésí ayé wọn. Ọ̀pọ̀ lára wa mọ ẹnì kan tó ní ìṣòro yìí. [Ṣí ìwé ìròyìn náà sí ibi tó ti sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí.] Ibí yìí sọ àwọn ohun tá a lè ṣe láti ṣèrànwọ́ bí èèyàn wa kan bá ní ìṣòro yìí.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́