Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Aug. 15
“A fẹ́ kó o sọ èrò rẹ̀ lórí gbólóhùn Jésù yìí. [Ka Mátíù 5:5.] Nígbà tí ìlérí yìí bá ṣẹ, ṣó o rò pé bí ayé ṣe rí yìí ló ṣì máa rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ọ̀nà tí Bíbélì sọ pé Jésù máa gbà tún ayé ṣe. Ó tún ṣàlàyé àwọn ẹni tó máa jogún ayé.”
Ile Iṣọ Sept. 1
“Ọ̀pọ̀ ò nífẹ̀ẹ́ sí ìsìn mọ́. Ṣó o rò pé ìsìn téèyàn bá ń ṣe ń mú kéèyàn sunwọ̀n sí i? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn kan á máa wá kiri nínú ìsìn láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. [Ka 2 Tímótì 4:3, 4.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bá a ṣe lè bọlá fún Ọlọ́run bá a bá ń ṣe ìsìn tòótọ́ àti oore tí ìsìn tòótọ́ ń ṣe wá.”
Jí! July-Sept.
“Lóde òní, ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó ló wà nínú ìṣòro. Ṣó o rò pé àǹfààní kan wà táwọn tọkọtaya lè rí bí wọ́n bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ yìí? [Ka Éfésù 4:32. Kó o wá jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò ìlànà Bíbélì tó bá àkókò yìí mu tó sì lè ràn wá lọ́wọ́ tá a fi máa ní ìdílé aláyọ̀.”
Bó o bá bá ọ̀dọ́ pàdé, o ò ṣe sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ ojúgbà ló ń ronú àtigbéyàwó. Ibo lo rò pé èèyàn ti lè rí àlàyé tó ṣeé gbà gbọ́ nípa ọ̀ràn yìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Kíyè sí ẹni tó fi ètò ìgbéyàwó lélẹ̀. [Ka Mátíù 19:6.] Ìwé ìròyìn yìí mẹ́nu ba ìlànà Bíbélì mélòó kan tó lè ràn wá lọ́wọ́ tá a fi máa ní ìdílé aláyọ̀.”