Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Aug. 15
“Màá fẹ́ mọ èrò ẹ lórí ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ. [Ka Hébérù 3:4.] Ṣó o gbà pé ẹni tí ọgbọ́n rẹ̀ ju tẹ̀dá lọ ló dá ayé? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ̀ bóyá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìgbàgbọ́ pé Ẹnì kan ló dá ayé yìí bára mu.”
Ile Iṣọ Sept. 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ìtàn tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú ‘Májẹ̀mú Láéláé’ á ràn wá lọ́wọ́ gan-an. Ṣùgbọ́n kò dá wọn lójú bóyá ìlànà inú rẹ̀ ṣì bóde òní mu. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kó fèsì, kó o wá ka Róòmù 15:4.] Ìwé ìròyìn yìí fi hàn pé àmọ̀ràn tó wà nínú ‘Májẹ̀mú Láéláé’ wúlò gan-an ní ìgbé ayé ẹ̀dá, ó sì tún ń fúnni ní ìrètí tó dájú nípa ọjọ́ ọ̀la.”
Jí! July–Sept.
“Màá fẹ́ mọ èrò ẹ nípa ẹsẹ Bíbélì yìí. [Ka 1 Tímótì 6:10.] Ṣó o rò pé kò ní lẹ́yìn bó bá jẹ́ pé owó àti dúkìá lèèyàn ń fi ojoojúmọ́ ayé lé? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé aburú tó wà nínú kéèyàn máa fi ojoojúmọ́ ayé lé ọrọ̀.”
“Kò sẹ́ni tí kò nílò owó láyé. Ǹjẹ́ o rò pé ó ṣeé ṣe kéèyàn dẹni tí owó gbà lọ́kàn? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ nípa ìlépa ọrọ̀. [Ka 1 Tímótì 6:10.] Ìwé ìròyìn yìí fún wa láwọn àbá wíwúlò mélòó kan nípa béèyàn ṣe lè máa lo ìwọ̀nba owó tó bá ń wọlé láìṣe jura ẹ̀ lọ.”