Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ Aug. 15
“Ta lo rò pé a lè jẹ́ adúróṣinṣin sí lọ́nà tó ga jù lọ? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Àpilẹ̀kọ yìí tẹnu mọ́ jíjẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run tòótọ́. [Tọ́ka sí ojú ìwé 5, kó o sì ka 2 Sámúẹ́lì 22:26.] Ǹjẹ́ o mọ̀ pé jíjẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run lè mú káwọn èèyàn yẹra fún híhùwà ìkórìíra sí àwọn ẹlòmíràn? Mo mọ̀ pé wàá gbádùn kíkà nípa kókó yìí.”
Jí! Sept. 8
“Ǹjẹ́ o ti ṣàníyàn rí pé pàǹtírí táwọn èèyàn ń kó jọ gegere ti pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ? [Jẹ kí ó fèsì.] Kókó pàtàkì kan tó ń fa ìṣòro yìí ni fífi nǹkan ṣòfò. Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti má ṣe jẹ́ ẹni tó máa ń fi nǹkan ṣòfò. [Ka Jòhánù 6:12.] Ìwé ìròyìn yìí fi hàn bí títẹ̀lé àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè ran àwọn ìdílé lọ́wọ́, kí wọ́n má bàa jẹ́ ẹni tó máa ń fi nǹkan ṣòfò.”
Ilé Ìṣọ́ Sept. 1
“Ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti kíyè sí i pé ní ọ̀pọ̀ àdúgbò, àwọn aládùúgbò kì í bìkítà nípa ara wọn mọ́ bó ti máa ń rí nígbà kan? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Jésù sọ ìlànà pàtàkì kan tó lè mú wa jẹ́ aládùúgbò rere. [Ka Mátíù 7:12.] Àwọn àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé bí a ṣe lè jẹ́ aládùúgbò rere àti bá a ṣe lè fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí láti jẹ́ bẹ́ẹ̀.”