Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ July 15
“Láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tí ẹ̀dá èèyàn ti ń gbé láyé, àìlóǹkà ẹ̀sìn ni wọ́n ti dá sílẹ̀. Ǹjẹ́ o rò pé ó ṣeé ṣe kéèyàn mọ èyí tó jẹ́ òótọ́ yàtọ̀ sí èké? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò ibi tó o ti lè rí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Ọlọ́run fọwọ́ sí.” Ka 2 Tímótì 3:16.
Ile Iṣọ Aug. 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà lónìí ló wà bí aláìsí. Kí lo rò pé a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò bí Bíbélì ṣe lè ran àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ tòótọ́.” Ṣàlàyé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó dúdú yàtọ̀ nínú àpilẹ̀kọ náà “Bíbélì Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́ Láti Rí Ayọ̀.”
Jí Aug. 8
“Ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ̀rù ń bà ní gbogbo ìgbà ṣáá. Kí lo rò pó fà á tí ẹ̀rù fi gbayé kan? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí dábàá tó wúlò nípa bá a ṣe lè dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ àwọn ewu tó wọ́pọ̀ lóde òní. Ó tún jíròrò àwọn ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì pé ayé máa tó bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù.” Ka Aísáyà 11:9.
“Ó bani nínú jẹ́ láti máa rí báwọn èèyàn ṣe ń jìyà látàrí àjálù tó ń ṣẹlẹ̀. [Fún un ní àpẹẹrẹ kan táwọn èèyàn mọ̀ ládùúgbò yín.] Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí pé ṣe làwọn àjálù yìí túbọ̀ ń pọ̀ sí i? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò ìbéèrè yẹn. Ó sì tún tu àwọn táwọn èèyàn wọn kú nínú irú àjálù bẹ́ẹ̀ nínú.” Ka Jòhánù 5:28, 29.