Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Ìṣọ́ July 15
“Lóde òní bí wọ́n bá sọ irú nǹkan báyìí nínú ìròyìn [àwòrán tó wà lẹ́yìn ìwé], ó dájú pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni yóò máa ṣiyèméjì. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Máàkù 4:39.] Kí ló fi hàn pé lóòótọ́ ni Jésù ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tó wà nínú Bíbélì? Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí dáhùn ìbéèrè yìí.”
Ile Ìṣọ́ Aug. 1
“Nítorí bí aráyé ṣe pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ, àwọn kan rò pé ọ̀nà kan ṣoṣo tá a lè gbà mú kí àlàáfíà jọba lágbàáyé ni pé kí ìjọba kan wà tí yóò máa ṣàkóso gbogbo ayé. Ǹjẹ́ o rò pé irú ohun bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Dáníẹ́lì 2:44.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí Ìjọba Ọlọ́run ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí àti bó ṣe máa sọ ayé di ibi àlàáfíà.”
Jí! Aug. 8
“Láyé tá a wà yìí, gbogbo ìgbà làwọn ọ̀daràn máa ń wá oríṣiríṣi ọgbọ́n ta láti lu àwọn tí kò bá fura ní jìbìtì. Ǹjẹ́ èyí kì í kọ ọ́ lóminú? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn Jí! yìí sọ àwọn ohun pàtàkì díẹ̀ tó lè ràn wá lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa lù wá ní jìbìtì.” Ka Òwe 22:3.
“Gbogbo wa lọkàn wa máa ń bà jẹ́ nígbà tá a bá gbọ́ bí wọ́n ṣe ń lo àwọn ọmọdé nílòkulò. Ó ṣeé ṣe kó o máa wò ó pé, ‘Ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run bìkítà nípa ẹ̀dá èèyàn?’ [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Sáàmù 72:12-14.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn ọmọdé àti bó ṣe máa mú ìtura ayérayé bá gbogbo àwọn tí wọ́n ń lò nílòkulò láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí.”