Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ July 15
“Ṣó o rò pé a lè rí ìjọba kan tó máa yanjú ìṣòro aráyé? [Jẹ́ kó fèsì.] Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wà nínú Mátíù 6:9, 10 [Kà á.] láti máa gbàdúrà pé kí irú ìjọba bẹ́ẹ̀ dé. Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tó jẹ́ kí Ìjọba Ọlọ́run dára ju gbogbo ìjọba èèyàn lọ, ó sì sọ rere tó máa ṣe ìran èèyàn.”
Ile Iṣọ Aug. 1
“Kò síbi téèyàn dé lónìí tí ò rí ẹni tó ń fojú ẹlòmíì gbolẹ̀. Ṣé o ò rò pé nǹkan á yàtọ̀ sí bó ṣe wà yìí táwọn èèyàn bá ń fi ọ̀rọ̀ Jésù yìí ṣèwà hù? [Ka Mátíù 7:12. Kó o wá jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká rí ohun tí Bíbélì sọ nípa bí ìran èèyàn á ṣe padà bẹ̀rẹ̀ sí í fún ọmọlàkejì lọ́wọ̀.”
Jí! July-Sept.
“Ǹjẹ́ ó ti ṣe ẹ́ rí bíi kó o béèrè pé, kí nìdí tá a fi ń darúgbó? [Jẹ́ kó fèsì.] Àlàyé tí Bíbélì ṣe lórí ìdí tá a fi ń darúgbó jẹ́ ká rí ètò tí Ọlọ́run ti ṣe sílẹ̀ ká lè gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun. [Ka Aísáyà 25:8.] Ìwé ìròyìn Jí! yìí ṣàgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára èrò táwọn èèyàn ní lásìkò yìí nípa ohun tó ń jẹ́ ká máa darúgbó.”
“Àwọn kan gbà gbọ́ pé ẹni tó bá máa rọ́nà gbé e gbà lódè òní gbọ́dọ̀ mọ béèyàn ṣe ń lejú. Àmọ́ wo bí ohun tí Jésù sọ ṣe yàtọ̀ síyẹn. [Ka Mátíù 5:5, 9.] Ṣó o gbà pẹ̀lú ohun tí Jésù sọ yìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé àǹfààní tó wà nínú kéèyàn jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 26 hàn án.