Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ July 15
“Ọ̀pọ̀ ti kíyè sí pé àṣà yíya ara ẹni láṣo ti túbọ̀ ń gbèrú sí i láàárín àwọn èèyàn. Ǹjẹ́ o rò pé ohun tó bọ́gbọ́n mu ni láti máa ṣe bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Kíyè sí ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n yìí nípa bí bíbá àwọn ẹlòmíràn kẹ́gbẹ́ ṣe ṣe pàtàkì. [Ka Oníwàásù 4:9, 10.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò ìdí tí gbogbo wa fi nílò ìbákẹ́gbẹ́ àwọn ẹlòmíràn, ó sì tún sọ bá a ṣe lè yanjú ìṣòro yíya ara ẹni láṣo.”
Jí! Aug. 8
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń kọminú lórí bí àwọn ohun tó ń rùfẹ́ ìbálòpọ̀ sókè ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ǹjẹ́ o rò pé ó tó nǹkan tó ń kọ èèyàn lóminú? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ tó wà nínú Bíbélì lè dáàbò bò wá. [Ka Éfésù 5:3, 4.] Ìwé ìròyìn yìí sọ bá a ṣe lè gba ara wa kúrò lọ́wọ́ ewu tó fara sin yìí.”
Ilé Ìṣọ́ Aug. 1
“Ǹjẹ́ o mọ̀ pé, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìròyìn kan sọ, owó tí ohun tó lé ní ìdajì àwọn tó ń gbé lórí ilẹ̀ ayé yìí ń ná lójúmọ́ kò tó igba ó lé àádọ́ta náírà [₦250]? Ṣé o rò pé ohun kan wà tá a lè ṣe láti yanjú ìṣòro yìí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ yìí ṣàlàyé ohun tí yóò fòpin sí ipò òṣì gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ ọ́.”—Ka Sáàmù 72:12, 13, 16.