Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní June: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tàbí Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? Tí ẹ kò bá ní àwọn ìwé yìí lọ́wọ́, ẹ lo ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! July àti August: Ẹ lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé méjìlélọ́gbọ̀n yìí: Tẹ́tí sí Ọlọ́run, Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? àti Ìwọ́ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! September: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!
◼ Tẹ́ ẹ bá ń kọ ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ní ìparí oṣù kọ̀ọ̀kan, ẹ máa ròyìn àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú àtàwọn ìwé ìkésíni tẹ́ ẹ bá fún àwọn èèyàn tàbí èyí tẹ́ ẹ fi sí ẹnu ọ̀nà àwọn tí kò sí nílé. Ẹ kọ ọ́ síbi tá a pè ní “Brochures and Tracts” nínú fọ́ọ̀mù tá a fi ń ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá. Tẹ́ ẹ bá rí ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ tẹ́ ẹ bá a sọ, tó sì gba ìwé wa, kódà bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé àṣàrò kúkúrú ló gbà, ó yẹ ká sapá láti padà lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò kí iná ìfẹ́ rẹ̀ má bàa kú.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ October 19, 2015, ìwé Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn la máa bẹ̀rẹ̀ sí í kà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ. Kí àwọn ìjọ tó bá fẹ́ gba àfikún ẹ̀dà ìwé yìí jọ̀wọ́ béèrè fún un tí wọ́n bá ń kọ̀wé béèrè fún àwọn ìwé tí wọ́n nílò. Kí àwọn tó bá fẹ́ ẹ̀dà EPUB wà á jáde lórí ìkànnì jw.org/yo dípò tí wọ́n á fi gba ẹ̀dà tá a tẹ̀ jáde.