Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ July 6
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 6
Orin 80 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 27 ìpínrọ̀ 1 sí 9 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 7-8 (8 min.)
No. 1: 1 Àwọn Ọba 8:27-34 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ọ̀nà Wo La Gbà Ń Kópa Nínú Ìmúṣẹ Hágáì 2:7? (5 min.)
No. 3: Tí Àníyàn Bá Ń Dà Ọ́ Láàmù Báwo Lo Ṣe Lè Fara Dà Á?—igw ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 1 sí 3 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: “Rántí àwọn ọjọ́ láéláé.”—Diu. 32:7.
10 min: Fi Àwọn Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù July. Ìjíròrò. Kọ́kọ́ fi àwọn àbá tó wà lójú ìwé yìí ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni. Lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Báwo La Ṣe Ṣe Sí? Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe jàǹfààní nígbà tí wọ́n lo àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà, “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I —Bó O Ṣe Lè Fi Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ẹnu Ọ̀nà.” Ní kí wọ́n sọ àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní.
Orin 67 àti Àdúrà