ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/15 ojú ìwé 3
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
km 6/15 ojú ìwé 3

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní June 29, 2015. A fi déètì tá a máa jíròrò kókó ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan sínú àwọn ìbéèrè náà kẹ́ ẹ lè ṣèwádìí wọn nígbà tẹ́ ẹ bá ń múra sílẹ̀ fún ilé ẹ̀kọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

  1. Kí ló burú nínú ọ̀nà tí Míkálì gbà bá Dáfídì sọ̀rọ̀, kí sì làwọn tọkọtaya lè rí kọ́ nínú ìtàn yìí? (2 Sám. 6:20-23) [May 11, w11 8/1 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 2]

  2. Báwo ló ṣe rí lára wòlíì Nátánì nígbà tí Jèhófà tún èrò rẹ̀ ṣe nípa ohun tó sọ fún Dáfídì pé kó lọ kọ́ tẹ́ńpìlì fún Jèhófà? (2 Sám. 7:2, 3) [May 11, w12 2/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 6 àti 7]

  3. Kí nìdí tí Nátánì fi ṣe àpèjúwe tó wà ní 2 Sámúẹ́lì 12:1-7 dípò kó kàn sọ ní tààràtà fún Dáfídì pé ó ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì? Báwo ni ìtàn yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ olùkọ́ tó túbọ̀ já fáfá? [May 18, w12 2/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 2 àti 3]

  4. Kí nìdí tó fi rọrùn fún Ábúsálómù láti rí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tàn jẹ? Kí la sì lè ṣe tá ò fi ní kó sọ́wọ́ àwọn tó fìwà jọ Ábúsálómù lóde òní? (2 Sám. 15:6) [May 25, w12 7/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 7]

  5. Báwo ni Jèhófà ṣe pèsè fún Dáfídì lásìkò tí ebi àti òùngbẹ hàn án léèmọ̀, kí lèyí sì kọ́ wa? (2 Sám. 17:27-29) [June 1, w08 9/15 ojú ìwé 5 sí 6 ìpínrọ̀ 15 àti 16]

  6. Kí la lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ Dáfídì bó ṣe bá ọmọ ilẹ̀ òkèèrè kan tó ń jẹ́ Ítítáì lò? (2 Sám. 18:2) [June 1, w09 5/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 7]

  7. Báwo làwọn àgbàlagbà tó wà nínú ìjọ ṣe lè jàǹfààní látinú àpẹẹrẹ Básíláì? (2 Sám. 19:33-35) [June 8, w07 7/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 1 àti 2]

  8. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ nípa ìdúróṣinṣin ṣe ń fi àwa ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní lọ́kàn balẹ̀? (2 Sám. 22:26) [June 15, w10 6/1 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 6 àti 7]

  9. Ọ̀nà wo ni Nátánì gbà fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, báwo ni àwa náà ṣe lè jẹ́ adúróṣinṣin lóde òní? (1 Ọba 1:11-14) [June 22, w12 2/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 1, 4 àti 5]

  10. Àwọn ọ̀nà wo nígbèésí ayé ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan ti lè ṣe bíi ti Sólómọ́nì, nípa fífi èrò tí kò tọ́ tan ara rẹ̀ jẹ, kó sì tipa báyìí ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run? (1 Ọba 3:1) [June 29, w11 12/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 12 sí 14]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́