Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ June 29
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 29
Orin 9 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 26 ìpínrọ̀ 18 sí 23, àti àpótí tó wà lójú ìwé 269 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 3-6 (8 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: “Rántí àwọn ọjọ́ láéláé.”—Diu. 32:7.
15 min: Ìwé Tá A Máa Lò Lóṣù July. Ìjíròrò. Sọ àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ìwé tá a máa lò, kó o sì ṣe àṣefihàn bí akéde kan ṣe ń ran ẹni tuntun kan lọ́wọ́ láti múra bó ṣe máa gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lóde ẹ̀rí sílẹ̀.
15 min: Jàǹfààní Nínú Ìwé Ọdọọdún 2015. Ìjíròrò. Ní ṣókí, sọ àwọn kókó tó wà nínú “Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí.” Ní kí àwọn ará sọ ohun tó wú wọn lórí nínú ìròyìn iṣẹ́ ìsìn kárí ayé. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n ka Ìwé Ọdọọdún náà tán.
Orin 108 àti Àdúrà