Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ June 22
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 22
Orin 67 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 26 ìpínrọ̀ 10 sí 17 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 1-2 (8 min.)
No. 1: 1 Àwọn Ọba 1:15-27 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìdí Táwọn Kristẹni Tòótọ́ Fi Ní Ìtẹ́lọ́rùn àti Ayọ̀—igw ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 1 sí 3 (5 min.)
No. 3: Níwọ̀n Bí Ìyè Ti Jẹ́ Ẹ̀bùn, Kí Nìdí Tó Fi Pọn Dandan Pé Ká Ṣiṣẹ́ Ìgbàlà Wa Yọrí?—Róòmù 6:23; Fílí. 2:12 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: “Rántí àwọn ọjọ́ láéláé.”—Diu. 32:7.
15 min: Àwọn Àṣeyọrí Wo La Ṣe? Ìjíròrò. Akọ̀wé ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Sọ àwọn àṣeyọrí tẹ́ ẹ ṣe lásìkò Ìrántí Ikú Kristi, kó o sì gbóríyìn fún àwọn ará fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe. Ní kí wọ́n sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń pín ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi.
15 min: Báwo Ni Jèhófà Ṣe Di Ọwọ́ Rẹ Mú? (Aísá. 41:13) Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tí wọ́n ti ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà bọ̀ láti ọjọ́ tó ti pẹ́. Kí wọ́n sọ bí Jèhófà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn.
Orin 107 àti Àdúrà