Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ June 15
“Ǹjẹ́ o rò pé pẹ̀lú ìṣòro tó ń kojú àwa ẹ̀dá, a ṣì lè láyọ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ibì kan tá a ti lè rí ìtọ́sọ́nà tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro tó ń bá wa fínra nígbèésí ayé. Ó tún jíròrò bí ojúlówó ìrètí ṣe lè gbé wa ró.” Ka Ìṣípayá 21:3, 4.
Ile Iṣọ July 1
“Nínú ayé tó kún fún wàhálà yìí, ìbéèrè tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń béèrè ni pé: ‘Ìṣòro tiẹ̀ ṣe wá kún inú ayé báyìí ná? Bí Ọlọ́run bá wà, kí ló dé tí ò tíì ṣe nǹkan kan láti fòpin sí ìyà tó ń jẹ wá yìí?’ Ṣé irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ ti wá sí ìwọ náà lọ́kàn rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn lọ́nà tó ṣe kedere látinú Bíbélì.” Ka 2 Tímótì 3:16.
Jí! Apr.-June
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sapá kí wọ́n lè láyọ̀, àmọ́ ó dà bíi pé àwọn tó ń ní ayọ̀ ọ̀hún ò ju díẹ̀ lọ. Ṣó o rò pé èyíkéyìí lára àwọn nǹkan tó wà níbí yìí lè mú kéèyàn ní ayọ̀ nígbèésí ayé? [Fi àpótí tó wà lójú ìwé 9 hàn án. Kó o wá ka ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fà yọ.] Ìwé ìròyìn Jí! yìí jíròrò àwọn ohun tó dà bíi kọ́kọ́rọ́ téèyàn lè fi ṣílẹ̀kùn ayọ̀.”